Dupe Jayesinmi
Ìrísí
(Àtúnjúwe láti Dúpẹ́ Jáyésinmi)
Dúpẹ́ Jáyésinmi tí yóò pé ọmọ ọdún ménìlélọ́gọ́ta (62) jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin ọmọ bíbí Ìjẹ̀bú igbó ni ìpínlẹ̀ Ògùn, ṣùgbọ́n tí àwọn òbí rẹ̀ bí sí ìlú Ìbàdàn ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. [1]
Ìgbà èwe àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Dúpẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní Seventh Day Adventist Primary School ní Ilé-Ìfẹ́ , ó tẹ̀ síwájú ní CAC Commercial High School tí wọ́n ń pè ní CAC High School ní ìlú Iléṣà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun. Bákan náà ó lọ sí Sight & Sound International School, Ìbàdàn, lẹ́yìn èyí ó kàwé gboyè nínú iṣẹ́ Akọ̀wé Ìbàdàn Polytechnic. "No Rival" ni àkọ́lé sinimá àgbéléwò tó mú kí ìràwọ̀ Dúpẹ́ Jáyésinmi tán síta. Láti ìgbà náà, ó ti kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sinimá àgbéléwò èdè Yorùbá. [2]. Ọmọ ìjọ Mímọ́ ni Dúpẹ́. [3]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Why I Chose To Live In IBADAN, Veteran Actress, DUPE JAIYESINMI Opens Up". City People Magazine. 2018-09-24. Retrieved 2020-01-06.
- ↑ "ACTRESSES ARE BEST HOUSEWIVES - DUPE JAYESINMI". Modern Ghana. 2008-03-16. Retrieved 2020-01-06.
- ↑ "35 Popular Entertainers Who Are Celestial Church Members (Photos) • Celestial News Online". Celestial News Online. 2017-04-14. Archived from the original on 2017-07-19. Retrieved 2020-01-06.