Iṣẹ́ loògùn ìṣẹ́
Iṣẹ́ loògùn ìṣẹ́ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ewì tí J.F Ọdúnjọ kọ.
Ewì iṣẹ́ loògùn ìṣẹ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Iṣẹ́ lòògùn ìṣe, múra síṣẹ́ ọ̀rẹ́ mi,
Bí a kò rẹ́ni fẹ̀yìn tì,
Bí ọ̀lẹ là á rí,
Bí a kò rẹ́ni gbẹ́kẹ̀lé,
A tẹra mọ́ṣẹ́ ẹni,
Ìyá rẹ le lówó lọ́wọ́,
Bàbá rẹ̀ sì lè ni ẹṣin léèkàn,
Bí o bá gbójú lé wọn,
O tẹ́ tán ni mo sọ fún ọ,
Ohun tí a kò bá jìyà fún,
Ṣé kì í lè tọ́jọ́,
Ohun tí a bá fara ṣiṣẹ́ fún,
Ni ń pẹ́ lọ́wọ́ ẹni.
Apá lará, ìgúnpá ni ìyekan,
Bí ayé bá ń fẹ́ ọ lónìí,
Bí o bá lówó lọ́wọ́,
Ni wọn á máa fẹ́ ọ lọ́la,
Tàbí o wà ní ipò àtàtà,
Ayé á yẹ́ ọ sí tẹ̀rín-tẹ̀rín,
Jẹ́kí o di ẹni tí ń ráágó,
Kí o rí bí ayé tí ń ṣímú sí ọ.
Ẹ̀kọ́ sì tún ń sọni dọ̀gá,
Múra kí o kọ́ ọ dáradára,
Bí o sì rí ọ̀pọ̀ ènìyàn,
Tí wọ́n ń fi ẹ̀kọ́ ṣe ẹ̀rín rí,
Ṣọ́ra kí o má fara wé wọn;
Ìyà ń bọ̀ fún ọmọ tí kò gbọ́n,
Ẹkún ń bẹ fún ọmọ tí ń sá kiri,
Má fi òwúrọ̀ ṣeré ọrẹ mi,
Múra sí iṣẹ́ ọjọ́ ń lọ.