Jump to content

Ìmọ̀ Ẹ̀rọ

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Imo Ero)

Sàláwù Ìdáyàt Olúwakẹ́mi

ÌMỌ̀ Ẹ̀RỌ

Bí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ bí akò bá sọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, a jẹ́ pé à ń rólé apá kan nìyẹn. Báwo ni a ó ò ṣe pé orí ajá tí a kò níí pe orí ìkòkò tí a fi ṣè é? ìmọ̀ sáyáǹsì ló bí ìmọ̀ ẹ̀rọ. Sáyáǹsì ni yóò pèsè irinsé tí ìmọ̀ ẹ̀rọ máa lo láti fi se agbára.

Ọ̀nà méjì ló yẹ kí á gbé àlàyé wa kà nígbà tí bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ.

(1) Ìmọ̀ ẹ̀rọ àbáláyé (Anciant technology)

(2) Ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé (Modern technology)

ÌMỌ̀ Ẹ̀RỌ ÀBÁLÁYÉ

Ní ìgbà àwọn baba ńlá wa, tí ojú sì wà lórúnkún, ọ̀nà láti wá ojútùú sí ìsòro tó wà láwùjọ bóyá nípa ilẹ́ gbígbé, asọ wíwọ̀ oúnjẹ jíjẹ ló fà á tí àwọn baba ńlá wà fi máa ń lo ìmọ̀ sáyéǹsì tiwańtiwa láti sẹ̀dáa àwọn nǹkan àmúsagbára lásìkò náà. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbà náà ló di iṣẹ́ ò òjọ́ tí àwọn baba ńlá wa ń ṣe lásìkò náà. Ẹ jẹ́ ki á mú lọkọ̀ọ̀kan.

Oúnjẹ jíjẹ

Yorùbá bọ̀ wọ́n ní:


“Ohun tá a jẹ́ làgbà ohun táá ṣe. Wọ́n á tún máa sọ pé bí oúnjẹ bá kúrò nínú ìṣẹ́, ìsẹ́ bùṣe”. Ìdí nìyí tí wọ́n fi wá ohun èlò lati máa ṣe àwọn iṣẹ́ òòjọ́ wọ́n bi Isẹ́ àgbẹ̀.

Ìṣẹ́ àgbẹ̀ ni isẹ́ ìlè wà. Àwọn baba ńlá wa máa ń lo oríṣìíríṣìí irin ìṣẹ́ láti wá ohun jíjẹ lára wọn ni àdá, ọkọ́, agbọ̀n, akọ́rọ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Iṣẹ́ Ọdẹ,

Iṣẹ́ ọdẹ jẹ́ iṣẹ́ idabọ fún ìran Yorùbá. Ìdí ni péwu ló jẹ́ nígbà náà. Iṣẹ́ àgbẹ̀ gan an ni ojúlówó iṣẹ́ nígbà náà lára àwọn irin-iṣẹ́ tí àwọn ọdẹ máa ń lo ni, ọkọ́, àdá, ìbon, òògùn àti àwọn yòókù.

ASỌ WÍWÒ.

Nígbà tí a ba jẹun yó tán, nǹkan tó kù láti ronú nípa rẹ̀ ni bí a oo se bo ìhòhò ara. Èyí ló fà á tí àwọn baba ńlá wa fi dọ́gbọ́n aṣọ híhun.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, awọ ẹran ni wọ́n ń dà bora lákòókó náà, ṣùgbọ́n wọn ní ọ̀kánjùá ń dàgbà ọgbọ́n ń rewájú ọgbọ́n tó rewájú ló fàá tí àwọn èèyàn fi dọ́gbọ́ aṣọ hihun lára òwú lóko. Láti ara aṣọ òfì, kíjìpá àti sányán ni aṣọ ìgbàlódé ti bẹ̀rẹ̀ ILÉ GBÍGBÉ.

Bí a bá bo àsírí ara tán ó yẹ kí á rántí ibi fẹ̀yìn lélẹ̀ si. Inú ihò (Caves) la gbọ́ pé àwọn ẹni àárọ̀ ń fi orí pamọ́ sí í ṣùgbọ́n bí ìdàgbà sókè ṣe bẹ̀rẹ̀, ni àwọn èèyàn ń dá ọgbọ́n láti ara imọ̀ ọ̀pẹ, koríko àti ewéko láti fi kọ́ ilé.

IṢẸ ARỌ́ (ALÁGBẸ̀DẸ)

Bí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ láwùjọ Yorùbá bí a kò mẹ́nu bà isẹ́ alágbẹ̀dẹ, a jẹ́ pé àlàyé wa kò kún tó. Iṣẹ́ arọ́ túmọ̀ sí kí a rọ nǹkan tuntun jáde fún ìwúlò ara wa. ọ̀pọ̀ nínú irinṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ tí àwọn àgbẹ̀ ńlò ló jẹ́ pé àwọn alágbẹ̀dẹ́ ló máa ń ṣe e. Irinsẹ́ àwọn ọ̀mọ̀lé, ahunsọ, àwọn alágbẹ̀dẹ ni yóò rọ̀ọ́ jáde. Irinse àwọn ọdẹ, àwọn ọ̀mọ̀lé àwọn alágbẹ̀dẹ ló ń rọ gbogbo rẹ̀.

Ìmọ̀ ẹ̀rọ gan-an lọ́dọ̀ àwọn alágbẹ̀dẹ ló ti bẹ̀rẹ̀. Tí a bá ṣe àtúpalẹ̀ Ẹ̀RỌ̣ yóò fún wa ni

ẹ - mofiimu àfòmọ́ ìbẹ̀rẹ̀

rọ - ọ̀rọ̀-ìṣe adádúró

ẹ + rọ ---- > ẹrọ.


Rírọ́ nǹkan ntun jáde ni èrọ ìmọ̀ sáyéǹsì gẹ́gẹ́ bí ń ṣe sọ ṣáájú ló bí ìmọ̀ ẹ̀rọ. Ó yẹ kí á fi kun un pé, ọpọ́n ìmọ̀ ẹ̀rọ ti sún síwájú báyìí. Ìdí èyí ni pé ìmọ̀ ẹ̀rọ to ti ọ̀dọ̀ àwọn òyìnbó aláwọ̀ funfun wá ti gbalégboko. Àwọn ọ̀nà tí a ń gbà pèsè nǹkan rírọ ti yàtò báyìí.

ÌMỌ̀ Ẹ̀RỌ ÌGBÀLÓDÉ

Lẹ́yìn ìgbà tí ọ̀làjú wọ agbo ilẹ́ Yorùbá ni ọ̀nà tí a ń gba ṣe nǹkan tó yàtọ̀. Ìmọ̀ ẹrọ àtòhúnrìnwá tí mú àyè rọrùn fún tilétoko. Ṣùgbọn ó yẹ kí á rántí pé ki àgbàdo tóó dáyé ohun kan ni adìyẹ ń jẹ. Àwọn nǹkan tí adìẹ ń jẹ náà lati ṣàlàyé nínú ìmọ̀ ẹ̀rọ àbáláyé. Iṣu ló parade tó diyán, àgbàdo parade ó di ẹ̀kọ. Ìlosíwájú ti dé bá imọ̀ ẹ̀rọ láwùjọ wa. Ẹ jẹ́ kí á wo ìlé kíkọ́ àwọn ohun èlò ìgbàlódé ti wà tí a le fi kọ́ ilé alájàmẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n tàbí ju bẹ́ẹ̀ lọ.

Ìmọ̀ ẹ̀rọ náà ló fáà tí àwọn mọ́tọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ fi dáyé. Àwọn nǹkan amáyédẹrun gbogbo ni ó ti wà. Ẹ̀rọ móhùnmáwòrán, asọ̀rọ̀mágbèsì, ẹ̀rọ tí ń fẹ́ atẹgun (Fan), ẹ̀rọ to n fẹ́ tútù fẹ́ gbígbóná (air condition) Àpẹẹrẹ mìíràn ni ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀, alagbeeka, ẹ̀rọ kòmpútà, ẹ̀rọ alukálélukako (Internet).

Gbogbo àwọn àpẹẹrẹ yìí ni ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé tíì máyé dẹrùn fún mùtúmùwà. Àwọn àléébù ti wọn náà wa, ṣùgbọ́n iṣẹ́ àti ìwúlò wọn kò kéré rárá.