James Baskett
James Franklin Baskett (ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kejì ọdún 1904 – ọjọ́ kẹsàn-án oṣù keje ọdún 1948) jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Òṣèré oní tíátà àti olórin ni pẹ̀lú. Ó kópa nínú eré Song of the South tí Disney ṣe àgbéjáde rẹ̀ ní ọdún 1946 gẹ́gẹ́ bíi Ọńkúú Remus tó kọ orin "Zip-a-Dee-Doo-Dah".
Fún ìdánimọ̀ lórí ipa tí ó kó gẹ́gẹ́ bíi Remus, ó gba àmì ẹ̀yẹ ní ọdún 1948, èyí tí ó sọ ó di òṣèré ọkùnrin-adúláwọ̀ tí ó kọ́kọ́ gba irú àmì ẹ̀yẹ báyìí.
Iṣẹ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ọ̀gbẹ́ni Baskett kẹ́kọ̀ọ́ famakọ́lọ́jì fún ìgbà díẹ̀ ní ìgbà ọ̀dọ́ ayé rẹ̀, ṣùgbọ́n ó fi ẹ̀kọ́ yìí sílẹ̀ láti lépa iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣèré oní tíátà. Ó kó lọ sí New York, láti pàdé Bill 'Mr. Bojangles' Robinson. Ní ọdún 1941, ó fi ohùn rẹ̀ ṣe Fats Crows nínú fíìmù àwọn ọmọdé tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Dumbo, ó sì tún kọ́pa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ B movies, bíi Revenge of the Zombies ní ọdún 1943, The Heavenly Body ní ọdún 1944, àti eré tí wọ́n ti lo èdè ìbílẹ̀ ti Orbon, tí àkọ́lé rè ń jẹ́ Jungle Queen ní 1945.[1][2]Làti ọdún 1944 títí dé ọdún1948, ó kópa pẹ̀lú àwọn mìíràn nínú ètò orí rédíò tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ Amos 'n' Andy Show gẹ́gẹ́ bíi agbẹjórò Gabby Gibson.Ní 1945,ó lọ fún ìdánwò-ìgbanisiṣẹ́ ti fíìmù titun Disney Song of the South (1946), tí ó dá lórí àwọn ìtàn Uncle Remus tí Joel Chandler Harris kọ. Lọ́gán ni Walt Disney rí ẹ̀bùn Baskett ó sì gbéṣẹ́ nàà fun-un lójú ẹsẹ̀.
Àtòjọ àwọn fíìmù rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ọdún | Àkọ́lé | Ipa | Ìsọníṣókí |
---|---|---|---|
1932 | Harlem Is Heaven | Money Johnson | Film debut; credited as Jimmy Baskette |
1933 | 20,000 Cheers for the Chain Gang | Vocalist | Uncredited |
1938 | Gone Harlem | unknown | Credited as Jimmie Baskette |
1938 | Policy Man | unknown | Credited as Jimmie Baskette |
1939 | Straight to Heaven | First Detective | |
1940 | Comes Midnight | unknown | |
1941 | Dumbo | Fats Crow (voice) | Uncredited |
1943 | Revenge of the Zombies | Lazarus | Alternative title: The Corpse Vanished |
1944 | The Heavenly Body | Porter | Uncredited |
1945 | Jungle Queen | Orbon | Credited as Jim Basquette |
1946 | Song of the South |
|
(final film roles) |
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Movies till Dawn: Almost Weirder Than Now". April 7, 2020.
- ↑ "Jungle Queen". April 16, 2015.