Jos Plateau
Jos Plateau jẹ́ ilẹ̀ òkè kan tí ó sún mọ́ àárín orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Wọ́n fún ilẹ̀ náà ní orúkọ rẹ̀ nítorí pé ó wà ní Ìpínlẹ̀ Plateau, àti nítorí Jos, olú-ìlú ìpínlẹ̀ Plateau. Ilẹ̀ òkè náà jẹ́ ilé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn pẹ̀lú oríṣi àṣà àti èdè.
Ilẹ̀ Jos Plateau
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Jos Plateau ní ilẹ̀ tí ó tó 8600 km². Gígún rẹ̀ kọjá òkun sì tó kìlómítà kan, òun ni ó tóbi jù nínú àwọn ilẹ̀ tí ó fi kìlómítà kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ kọjá òkun ni Nàìjíríà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ odò ní orísun wọn láti Jos plateau. Àwọn odò bi Odò Kaduna, Odò Gongola.
Àwọn ènìyàn tí ó ń gbé ibẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Jos Plateau súnmọ́ àárín Nàìjíríà, ó sì tó àwọn oríṣiríṣi ẹ̀yà ọgọ́ta tí ó ń gbé ní ilẹ̀ [1] Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èdè tí wọ́n ń sọ níbẹ̀ jẹ́ àwọn èdè tí ó jọ mọ́ èdè Chad.[2] Méjì nínú àwọn èdè tí wọ́n ń sọ jù níbẹ̀ ni èdè Berom àti èdè Ngas. Àwọn èdè míràn ni Mwaghavul, Pyem, Ron, Afizere, Anaguta, Aten, Irigwe, Chokfem, Kofyar, Kulere, Miship, Mupun àti Montol.
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ State., Better Life Programme (Nigeria). Plateau (c. 1992). Traditional dishes, snacks, drinks & herbs from Plateau State.. [Better Life Programme, Plateau State]. OCLC 29704741. http://worldcat.org/oclc/29704741.
- ↑ Isichei, Elizabeth (1982). "Introduction". In Studies in the History of Plateau State, Nigeria, ed. by Elizabeth Isichei, pp 1–57. Macmillan, London.