Orílẹ̀-Èdè Yorùbá
Ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, àwọn ènìyàn Yorùbá wà káàkiri ìpínlẹ̀ bí i mẹ́sàn-án. Àwọn ìpínlẹ̀ náà ni Ẹdó, Èkó, Èkìtí, Kogí, Kúwárà, Ògùn, Òndò, Ọ̀ṣun àti Ọ̀yọ́.
Lóde òní, Yorùbá wà káàkiri ilẹ̀ àwọn aláwọ̀ dúdú (Áfíríkà), Amẹ́ríkà àti káàkiri àwọn erékùsù tí ó yí òkun Àtìlántíìkì ká. Ní ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú. A le ríwọn ní Nàìjíríà, Gáná, Orílẹ̀-Olómìnira Bẹ̀nẹ̀, Tógò, Sàró àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà àti àwọn erékùsù káàkiri, a lè rí wọn ní jàmáíkà, Kúbà, Trínídáádì àti Tòbégò pẹ̀lú Bùràsíìlì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Yàtọ̀ sí ètò ìjọba olósèlú àwarawa tí ó fi gómìnà jẹ olórí ní ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan, a tún ní àwọn ọba aládé káàkiri àwọn ìlú nlánlá tí ó wà ní ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Díẹ̀ lára wọn ni Ọba ìbíní, Ọba Èkó, Èwí tí Adó-Èkìtì, Òbáró ti Òkéné, Aláké tí Abẹ́òkúta, Dèji ti Àkúrẹ́, Olúbàdàn ti Ìbàdàn, Àtá-Ója ti Òṣogbo, Sọ̀ún ti Ògbòmọ̀ṣọ́ ati Aláàfin ti Ọ̀yọ́.
Baálẹ̀ ní tirẹ̀ jẹ́ olórí ìlú kékeré tàbí abúlé. Ètò ni ó sọ wọ́n di olórí ìlú kéréje nítorí pé Yorùbá gbàgbọ́ pé ìlú kìí kéré kí wọ́n má nìí àgbà tàbí olórí. Aláàfin ni a kọ́kọ́ gbọ́ pé ó sọ àwọn olórí báyìí di olóyè tí a mọ̀ sí baálẹ̀.
Lábẹ́ àwọn olórí ìlú wọ̀nyí ni a tún ti rí àwọn olóyè orísìírísìí tí wọ́n ní isẹ́ tí wọ́n ń se láàrín ìlú, ẹgbẹ́, tàbí ìjọ (ẹ̀ṣìn). Lára irú àwọn oyè bẹ́ẹ̀ ni a ti rí oyè àjẹwọ̀, oyè ogun, oyè àfidánilọ́lá, oyè ẹgbẹ́, oyè ẹ̀ṣìn àti oyè ti agboolé bíi Baálé, Ìyáálé, Akéwejẹ̀, Olórí ọmọ-osú, Ìyá Èwe Améréyá, Mọ́gàjí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.