Oníṣe:Adeola Abiola
Adéọlá Abíọ́lá (Treasure), jẹ́ ọmọ ìpínlẹ̀ Èkìtì, o fẹ́ràn láti máa gbé èdè àti àṣà Yorùbà ga nípa ṣíṣe àmúlò àwọn nkan ẹ̀ṣọ́ tí ó jé ti ilẹ̀ wa àti ìgbélárugẹ wọn pàápàá jùlọ aṣọ wíwun, rírán àti wíwọ̀.
Akẹ́kọ̀ọ́ ni Adéọlá Abíọ́lá jẹ́ ní ilé-ìwé gíga ti Afe Babalola, Ado-Ekiti (pẹ̀lú àfojúsùn oyè Ọ̀mọ̀wé) nínú èka sáyẹ́nsì tí a mọ̀ sí Kémísírì.
Onímò àti akékọ̀ó gba ìwé-ẹ̀rí ni nínú ètò ẹ̀kọ́ kan tí Ìjoba Ámẹ́ríkà gbékalẹ̀ tí a mọ̀ sí International Visitor Leadership Program (IVLP) tí ó ró ogún àsàyàn aránṣọ káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lágbára nípa mímú ìdàgbàsóké bá ọrọ̀-ajé ní ẹ̀ka aṣọ rírán àti wíwọ̀ ní ọdun 2021. [1]
Adéọlá Abíọ́lá jẹ́ Aláṣẹ àti olùdarí ilé-iṣé aránṣọ tí a mọ̀ sí Treasure Stitches. Akọ́sẹ́mọṣẹ́-oníṣẹ́ ọwọ́, aránṣọ, afuńnilásọ àti aṣàfihàn aṣọ fún àwọn obìrin jànkàn láwùjọ. ó sì tún jé ẹni tí on ṣagbátẹrù-ṣèpolówo wíwọ̀ àti lílo àwọn aṣọ tí a ṣe ní ìbílẹ̀ wa ní ojoojúmọ́ (kí ó ma se jé ohun àmúròde-ẹ̀yẹ nìkan) [2] bí àpẹ̀ẹrẹ, Aṣọ-òkè abbl.
Adéọlá Abíọ́lá jé alákòso àti apàtẹ-ètò lóríí ayélujára ní ìkànnì, Facebook, Youtube ati instagram tí orúkọ ìdánimò rè jé sewing limited, níbití ó ti nṣe àfihàn àkójọpọ̀ ìrírí àti ìmọ̀ tí o ti ní nípa aṣọ rírán àti wíwọ̀.[3]
Adéọlá Abíọ́lá jé aya lọ́ọ̀dẹ́ ọkọ àti ìyá àwọn ọmọ méjì takọtabo.
- ↑ "US Consulate Honours 20 Nigerian Fashion Designers – THISDAYLIVE". THISDAYLIVE – Truth and Reason. 2021-10-03. Retrieved 2023-02-14.
- ↑ "launch of erelu attires by treasure stitches". Google Search. 2022-02-22. Retrieved 2023-02-14.
- ↑ "@sewinglimited70". Google Search. 2005-02-14. Retrieved 2023-02-14.