Jump to content

Àjẹsára ṣegede

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Àjẹsára ṣegede a má a dènà àrùn ṣegede láìséwu. Bí a bá lòó fún ọ̀pọ̀lọpọ̀, wọn a má a dín ìnira tíì bá wáyé nípasẹ̀ àrùn náà kù láàárín àwùjọ.[1] Ipá rẹ̀ bí a bá lòó fún ìwọ̀n ènìyàn tó tó 90% láàárín àwùjọ kan ni a ṣírò sí bíi 85%.[2] Ìwọ̀n egbògi náà méjì ni a nílò láti dènà àrùn náà fún ìgbà pípẹ́. Ìwọ̀n egbògi àkọ́kọ́ ni a dámọ̀ràn fún lílò láàárín ìgbà tí ènìyàn bá ti pé ọmọ oṣù 12 sí 18. Ìwọ̀n egbògi kejì ni a ó ò fúnni láàárín ìgbà tí ènìyàn bá di ọmọ ọdún méjì sí ọmọ ọdún mẹ́ẹ́fà.[1] Lílò rẹ̀ lẹ́yìn tí ènìyàn bá ti wà ní sàkání ibití àrùn náà ti wáyé, fún àwọn tí kò tíì ní agbára àti kojú àrùn tẹ́lẹ̀ rí, jẹ́ ohun tí yóò wúlò púpọ̀.[3]

Ààrùn Segede

Àjẹsára ṣegede jẹ́ èyítí kò léwu láti lò, àwọn àtúnbọ̀tán rẹ̀ kìí sì ní ipá rárá.[1][3] Ó lè fa ìrora díẹ̀ pẹ̀lú wíwú ojú ibi abẹ́rẹ́, àti ibà díẹ̀. Àwọn àtúnbọ̀tán tó burú ju ìwọ̀nyí lọ kò wọ́pọ̀.[1] Kò sí ẹ̀rí tó tó láti so àjẹsára náà pọ̀ mọ́ ìnira tó jẹ mọ́ àwọn àìsàn inú iṣan-ara.[3] A kò gbọdọ̀ fún àwọn tó ní oyún tàbí tí agbára àti kojú àkóràn àìsàn wọn ti dínkù pátápátá ní àjẹsára náà.[1] Ìfèsì ara lọ́nà tó burú láàárín àwọn ọmọ tí ìyá wọn gba àjẹsára náà nígbà tó lóyún; ni a kò tíì ní àkọsílẹ̀ kankan nípa rẹ̀.[1][3] Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a pilẹ̀ àjẹsára náà nínú sẹ́ẹ̀lì adìẹ, a lè lòó fún àwọn tó ní ìfèsì ara lọ́nà òdì sí ẹyin.[3]

Púpọ̀ lára àwọn orílẹ̀-èdè tó tí ní ìtẹ̀síwájú àti ọ̀pọ̀ lára àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣì ń tẹ̀síwájú a má a fikún ara ètò àjẹsára wọn, nígbà púpọ̀, ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú àjẹsára àrùn ìta (measles) àti ti rubella (àrùn ìta ti Jamini) tí a mọ̀ sí MMR.[1] Àdàlù àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí pẹ̀lú àjẹsára varicella (kòkòrò àrùn àìlèfojúrí tí ń fa ọfà ṣọ̀pọ̀nna tàbí ilẹ̀gbóná) tí a mọ̀ sí MMRV náà wà pẹ̀lú.[3] Ní ọdún 2005 orílẹ̀-èdè 110 ni ó pèsè àjẹsára náà ní oríṣi yìí. Ní àwọn agbègbè tí a tí ń fún àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ní àjẹsára náà, ìwọ̀n ìtànkálẹ̀ àrùn náà ti dínkù sí iye tó ju 90% lọ. Ó fẹ́rẹ̀ tó ìdajì bílíọ̀nù ìwọ̀n oríṣi àjẹsára náà kan tí a tí fún àwọn ènìyàn.[1]

A fúnni ní ìwé-àṣẹ àkọ́kọ́ fún àjẹsára ṣegede ní ọdún 1948; ṣùgbọ́n èyí kò ṣiṣẹ́ fún ìgbà pípẹ́.[3] Àwọn àjẹsára tí a mú dára síwájú síi di ohun tó wà fún lílò ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ní àwọn ọdún 1960. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àjẹsára àkọ́kọ́ jẹ́ Oríṣi tí a fi kòkòrò afàìsàn àìlèfojúrí tí a ti pa ṣe, àwọn àgbéjáde tó tẹ̀lé èyí jẹ́ àwọn tí a fi kòkòrò afàìsàn àìlèfojúrí tó ṣì wà láàyè, ṣùgbọ́n tí a ti sọ di aláìlágbára, ṣe.[1] Ó wà lórí Àkójọ Àwọn Egbògi Kòṣeémáàní ti Àjọ Ìlera Àgbáyé, àwọn òògùn tó ṣe pàtàkì jùlọ tí a nílò fún ètò ìlera ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ yòówù.[4] Àwọn oríṣiríṣi rẹ̀ ni ó ti wà fún lílò láti bíi ọdún 2007.[1]

  1. 1.00 1.01 1.02 1.03 1.04 1.05 1.06 1.07 1.08 1.09 "Mumps virus vaccines."
  2. Hviid A, Rubin S, Mühlemann K (March 2008).
  3. 3.0 3.1 3.2 3.3 3.4 3.5 3.6 Atkinson, William (May 2012).
  4. "WHO Model List of EssentialMedicines" (PDF).