Jump to content

Ìmò Ìṣírò

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Oju Ewe Imo Isiro

Ìmọ̀ Ìsirì je eyi t'on je mo nipa ọ̀pọ̀iye (quantity), nipa òpó (structure), nipa iyipada (change) ati nipa ààyè (space). Idagbasoke imo Isiro wa nipa lilo àfòyemọ̀ọ́ (abstraction) ati Ọgọ́bn ìrọ̀nú, pelu onka, isesiro, wiwon ati nipa fi fi eto s'agbeyewo bi awon ohun se ri (shapes) ati bi won se n gbera (motion). Eyi ni awon Onimo Isiro n gbeyewo, ero won ni lati wa aba tuntun, ki won o si fi otoo re mule pelu itumo yekeyeke.

A n lo Imo Isiro ka kiri agbaye ni opolopo ona ninu Imo Sayensi, Imo Ise Ero, Imo Iwosan, ati Imo Oro Okowo. Bi a se n lo imo Isiro bo si apa eyi ti a n pe ni Imo Isiro Lilo (Applied Mathematics). Apa keji Imo Isiro ni a mo si Imo Isiro Ogidi. Eyi je mo eko imo isiro to ko ti ni ilo kankan bo tileje pe o se se ki a wa ilo fun ni eyinwa ola.