Àjọ̀dún Fanti Ní Ìpínlẹ̀ Èkó

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Àjọ̀dún Fanti Ní Ìpínlẹ̀ Èkó tí wọ́n tún máa ń pè ní Àjọ̀dún Kàrétà Èkó tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Lagos Carnival lédè Gẹ̀ẹ́sì,[1] jẹ́ Àjọ̀dún tí ó gbajúmọ̀ jùlọ ìwọ oòrùn Afíríkà. Àjọ̀dún yìí máa ń wáyé nígbà Àjọ̀dún Lagos Black Heritage Festival, èyí ni Àjọ̀dún alárinrin agbáṣà àti ìṣe ìbílẹ̀ ga tí ó máa ń wáyé lọ́dọọdún. Ìṣẹ̀dálẹ̀ Àjọ̀dún Fanti bẹ̀rẹ̀ ní Erékùṣù Èkó nígbà ìṣèjọba àwọn òyìnbó amúnisìn àti àsìkò okoowò ẹrú ní sẹ́ńtúrì ókàndínlógún sẹ́yìn, nígbà tí àwọn ẹrú tí wọ́n kó lọ sí orílẹ̀ èdè Brazil padà bọ́ sí ilé. Ọdún 2010 ni wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣodún yìí padà lẹ́yìn tí wọn kò ṣe é fún ẹgbẹlẹmùkú ọdún. [2] Erékùṣù Èkó ní ìpínlẹ̀ Èkó ni Àjọ̀dún yìí tí máa ń wáyé. Oríṣiríṣi ìmúra àṣà pẹ̀lú aṣọ aláràǹbarà ni àwọn ènìyàn máa ń wọ̀ lásìkò Àjọ̀dún yìí. Oríṣiríṣi ijó, ìlù àti orin ìbílẹ̀ ni ó máa ń wáyé lásìkò ọdún yìí. Àmúlùmálà àṣà Yorùbá àti Brazil ni wọ́n máa ń gbé lárugẹ nígbà ọdún Fanti ni erékùṣù Èkó. [3][4][5]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. K. K. Prah (2009). Back to Africa: Afro-Brazilian returnees and their communities. Centre for Advanced Studies of African Society Cape Town (CASAS). ISBN 978-1-920-4474-58. https://books.google.com/books?id=V8JOAQAAIAAJ&q=caretta+carnival+lagos&dq=caretta+carnival+lagos&hl=en&sa=X&ved=0ahUKEwic1IH5iM7LAhUBEJoKHQe0CLYQ6AEIGjAA. 
  2. Kerstin Pinther; Larissa Förster; Christian Hanussek; Rautenstrauch-Joest-Museum; IWALEWA-Haus (Bayreuth, Germany); Goethe-Institut (Nairobi, Kenya). Afropolis: City. Jacana Media, 2012. p. 142. ISBN 9781431403257. https://books.google.com/books?id=9lcn62brtGQC&pg=PA142&dq=. 
  3. "The Lagos Carnival – a grand street party". I Love Lagos. Archived from the original on 2019-06-29. Retrieved 2020-02-09. 
  4. Monica Mark (8 May 2015). "Lagos locals fear annual carnival's links to Brazilian past are being lost". United Kingdom: The Guardian. https://www.theguardian.com/world/2015/may/08/locals-lagos-fear-carnival-forgotten-links-to-brazilian-past-nigeria. Retrieved 20 March 2016. 
  5. Omolara Omosanya. "Lagos Carnival adds colour to Easter celebrations". Radio Lagos. Radio lagos. Archived from the original on 2017-01-27. Retrieved 2020-02-09.