Ìsìnrú ní Gríkì àtijọ́

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ìsìnrú jẹ́ ohun tí ó wọ́pọ̀ Gríkì láyé àtijó, bí ó ti wọ́pọ̀ ní àwọn àwùjọ míràn nígbà náà.[1] Àwọn iṣẹ́ tí wọ́n ń lọ àwọn ẹrú fún ni iṣẹ́ àgbẹ̀, iṣẹ́ kùsà àti gẹ́gẹ́ bi ọmọ ọ̀dọ̀ fún iṣẹ́ nínú ilé.[2]

Ní Gríkì àtijọ́, wọn kò ka ẹrú mọ́ ara àwùjọ ṣùgbọ́n wọ́n rí wọn gẹ́gẹ́ bi ohun ìní.[3] Ọ̀pọ̀ ẹrú kò lẹ́tọ́ lọ́wọ́ ara wọn, wọ́n sì wà lábé olówó wọn tí ó le rà wọ́n, tà wọ́n, tàbí yá wọn fún ẹlòmíràn.[4]

Ìgbìyànjú láti ṣe ìwádìí nípa Ìsìnrú ní Gríkì àtijọ́ ti bá àwọn ìṣòro pàdé.[5] Àwọn àkọsílẹ̀ nípa ìsìnrú nígbà náà tako ara wọn, ọ̀pọ̀ wọn sì dá lórí ilẹ̀ Athens nìkan.

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Polakoff, Murray E.; Dhrymes, Phoebus J. (1958). "The Economic and Sociological Significance of Debt Bondage and Detribalization in Ancient Greece". Economic Development and Cultural Change 6 (2): 88–108. doi:10.1086/449759. ISSN 0013-0079. JSTOR 1151738. https://www.jstor.org/stable/1151738. 
  2. Morris, Sarah P.; Papadopoulos, John K. (2005). "Greek Towers and Slaves: An Archaeology of Exploitation". American Journal of Archaeology 109 (2): 155–225. doi:10.3764/aja.109.2.155. ISSN 0002-9114. JSTOR 40024509. https://www.jstor.org/stable/40024509. 
  3. Hunt, Peter (2016-12-19). "Slaves or Serfs?". On Human Bondage: 55–80. doi:10.1002/9781119162544.ch3. ISBN 9781119162483. http://dx.doi.org/10.1002/9781119162544.ch3. 
  4. "Modern Day Abolition – National Underground Railroad Freedom Center". freedomcenter.org. Retrieved 2023-03-12. 
  5. Hunt, Peter. Ancient Greek and Roman slavery.. ISBN 978-1-78785-697-4. OCLC 1176434948. http://worldcat.org/oclc/1176434948.