Ògún Festival

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ọdún Ògún jẹ́ ayẹyẹ ọdọọdún tí áwọn ènìyàn Yorùbá ìpínlẹ̀ Oǹdó, Nàìjíríà máa ń ṣe fún bíbu iyì fún Ògún, jagunjagun àti irúnmọlẹ̀ oníṣẹ́ irin tí àwọn Yorùbá gbà pé òun ni òrìṣà tí ó kọ́kọ́ dé ilé ayé.[1]

Ìtàn rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Gẹ́gẹ́ bíi ìgbàgbọ́ àwọn Yorùbá, Ògún jẹ́ ọba ó sì jẹ́ bàbá Ọ̀rànmíyàn òun sì tún ni ènìyàn àkọ́kọ́ láti dé sí ilé ayé; Ó sàmúlò àdá àti ajá láti yẹ ọ̀nà fún àwọn Irúnmọlẹ̀ yòókù láti kọjá. Òun ni wọ́n tún sọ pé ó ṣe ìkádìí iṣẹ́ lára àwọn ènìyàn àkọ́kọ́ tí Ọbàtálá dá, Òòṣà aṣẹ̀dá àwọn Yorùbá. Ọdún rẹ̀ máa ń sáábà wáyé láàrin oṣù kẹjọ tàbí oṣù kẹsàn-án ní ìpínlẹ̀ Oǹdó àti àwọn apá ibìkan ní ìpínlẹ̀ Èkìtì

Ìpalẹ̀mọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìpalẹ̀mọ́ fún ayẹyẹ ọdún bẹ̀rẹ̀ láti ó ku ìtàdógún, àwòrò Ògún yóò kéde rírí oṣù tuntun (èyí tí wọ́n gbọ́dọ̀ rí kí wọ́n tó lè bẹ̀rẹ̀ ọdún) nípa fífọn ùpé (fèrè ìbílẹ̀) fún ọjọ́ méje. Ọjọ́ kẹsàn-án lẹ́yìn tí wọ́n ti rí oṣù tuntun, ọba yóò rán ikọ̀ lọ láti lọ kéde ayẹyẹ ọdún. Lára ìpalẹ̀mọ́ fún ọdún ni títún afárá ṣe àti yíyẹ ọ̀nà. Ọdún ń tẹ̀ síwájú pẹ̀lú àìsùn Ìlagùn, Asorò tàbí àìsùn Ògún tí ó máa ń wáyé ní ọjọ́ Ògún ku ọ̀tunla. Àwọn alágbẹ̀dẹ ìlú Ifẹ̀ yóò kó àdá tuntun, ọkọ́ àti saworo wá, wọ́n ó sì fi ẹfọ́n, owó ẹyọ àti àwọn nǹkan mìíràn ṣe ẹwà sí ojúbọ. Wọ́n á ta ọtí sí òòṣà, wọ́n á jó yíká ojúbọ wọ́n á sì wúre. Wọ́n á pèsè ajá fún ìrúbọ.[2]

Ọdún ga-an[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọjọ́ mẹ́ta tí ó gbẹ̀yìn ọdún yìí máa ń lágbára. Àkọ́kọ́ nínú ọjọ́ yìí ni wọ́n a pa ajá tí ó jẹ́ kókó ọdún náà. Ènìyàn méjì yóò fa ajá náà bí ẹni pé wọ́n ń fà á mọ́ ara wọn lọ́wọ́ wọ́n á jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ̀ máa lọ díẹ̀díẹ̀ pẹ̀lú ìnira. Ìgbà mírán àwòrò Ògún yóò fi àdá bẹ́ ajá yìí kí ó tó kú fúnra rẹ̀. Wọ́n á po ẹ̀jẹ̀ ajá yìí pọ̀ pẹ̀lú iyọ̀, orógbó, ẹmu àti epo pupa wọ́n á dàá sí orí irinṣẹ́ àwọn olùsìn rẹ̀ èyí tí wọ́n ti kó sínú abọ́ kan; wọ́n gbàgbọ́ pé èyí kòní jẹ́ kí wọ́n rí ìyọnu tí yóò sì tún mú wọn jẹ èrè tabua. Ògún ni bàbá àwọn tí wọ́n ń sàmúlò irin nínú iṣẹ́ òòjọ́ wọn, bíi alágbẹ̀dẹ, awakọ̀, mẹkálíìkì àti àwọn oníṣẹ́ abẹ. Ọdún tún lè wáyé ní ibikíbi bí ó ṣe jẹ́ pé àwòrò máa ń ṣe ọdún yìí ní Àbújá ní ìgbà míràn láìtẹ̀lé àṣẹ ìtàdógún tí wọ́n máa ń lò

Àwọn ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "The Ogun Festival » Facts.ng". Facts.ng. 2014-09-23. Retrieved 2018-11-26. 
  2. "Ogun Festival". ZODML. 2017-10-04. Archived from the original on 2018-01-13. Retrieved 2018-11-26.