Ẹ̀rìn-Ilé

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ẹ̀rìn-Ilé jẹ́ ìlú kan ní apá àrin gbùngbùn Gúsù ní ìpínlẹ̀ Kwárà, ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[1].

Mòjé College of Education[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Mòjé College of education ni ó jẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tí ó ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nímọ̀ ìkọ́ni tí ó je ti ìjọba ní ó kalẹ̀ sí ìlú Ẹ̀rìn-ilé. Ilé ẹ̀kọ́ náà ni ó ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ ìkó́ni, èdè, ìmọ̀ ẹ̀rọ, ìmọ̀ ọnà àti ìmọ̀ bí a ti ṣe ń  to àwùjọ.[2]

Ìjà ìgboro Ẹ̀rìn pẹ̀lú Ọ̀fà[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

[3] Oríṣiŕiṣi ìjà ìgboro ló ti wáyé láàrín Ọ̀fà pẹ̀lú Ẹ̀rìn-ilé lórí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ láti ǹ kan bí ọdún 1973, tí ilé ẹjọ́ àgbà sì ti dá ẹjọ́ ọ̀rọ̀ náà. Àmọ́ ní ọdún 2013, ọ̀rọ̀ tún bẹ́yìn yọ nígbà ìlú méjèjì kọlu ara wọn tí wọ́n ti ilé ẹ̀kọ́ gbogbo-nìṣe (Federala Polytechninc, Ọ̀fà) pa àti àwọn ilé ìtajà, ilé ìjọsìn àti àwọn ilé iṣẹ́ ìjọba gbogbo ni kò ṣiṣẹ́ látàrí ìjà ìgboro tí ó wáyé ní ọdún náà. Adìyẹ bà lókùn tán, ara kò rọ okùn Ọ̀fà, bẹ́ẹ̀ lara kò rọ adìyẹ Ẹ̀rìn-ilé lọ̀rọ̀ náà.[4]

Àwọn ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Erin-Ile". 1World Map. Archived from the original on 19 April 2018. Retrieved 19 April 2018. 
  2. Moje, College of Education. "Admission is Ungoing". Moje College of Education. Moje College of Education. Archived from the original on 18 July 2018. Retrieved 18 July 2018. 
  3. "Ẹda pamosi". https://www.mce.edu.ng/. Moje College of Education. Archived from the original on 18 July 2018. Retrieved 18 July 2018.  External link in |website= (help)
  4. Akinola, Oluyi. "How we survived Offa-Erin Ile crisis". nationonlineng.net. Retrieved 19 April 2018.