Aalo

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ààlọ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìfáàrà[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ilẹ̀ Yorùbá, ní ìgbà tí kò tíì sí ètò mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà tí ó wà lóde òní, ọ̀rọ̀ àt'ẹnu dé ẹnu ni àwọn baba nla wa ma n fi n ṣe akọsile àwon ìṣẹ̀lẹ̀ ti o ba ṣẹ. Won a máa fi iru itan ti wọn bá lẹnu àwọn baba won yii fun iran ti o ba tẹle won. Fun apẹrẹ, awọn baba yoo sọ itan fun awon ọmọ won, nigba ti iru ọmọ bẹẹ na ba si di baba, oun naa yoo sọ iru itan bẹẹ fun awọn omo tirẹ naa. Lara iru awọn ọrọ àt'ẹnu d'ẹ́nu ti a n sọ ni itan, arọba ati ààlọ́. Ni ojú ewé yii, ààlọ́[1] ni a o ma gbé yẹ̀wò.

Ààlọ́ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn onírúurú ọ̀nà ti àwọn Yorùbá ma n gba ṣe ìtọ́ni, ìkìlọ̀, ìbániwí, ati bẹẹ bẹẹ lọ fun àwọn eniyan wọn. Ààlọ́ jẹ́ itan tó n ṣe akawe ohun kan pelu ekeji. Lọpọlọpọ igba, Ààlọ́ a maa nii ṣe pẹlu eranko si eranko, eranko si eniyan, tabi awon oun abẹmi miran ti Aṣẹda da sinu aye, lẹẹkọọkan ààlọ́ a maa jẹ mọ́ awọn ẹda ti a ko le fi oju lasan ri.

Pèpele tí a gbé ààlọ lé jẹ́ igba laelae nigba ti a gbagbọ wipe eniyan ati ẹranko n sọ ede kanna. Ni akoko yii, a gbagbọ wipe ọrun ati aye sun mo ara wọn to bẹẹ ti irinajo lọ bọ ko ṣoro fun eniyan tabi fun ẹranko nitoripe a gbagbọ wipe ọkan eniyan ko kun fun ẹgbin ati iwa ika bi ode oni[2].

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. https://yorubafolktales.wordpress.com/
  2. https://www.scribd.com/book/325976572/Yoruba-Folk-Tales