Aalo obìnrin alaigboran

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ọmọbìnrin Aláìgbọràn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ààlọ́ ooooo

Àalọ̀

Àlọ́ yí dá fìrìgbagbo, ó dá lórí ọmọbìnrin aláìgbọràn kan. [1]

Ni ayé àtijó,ọmọbìnrin kan wà ní ìlú kan. Ọmọbìnrin yìí rẹwà bí egbin. Gbogbo àwọn ọmọkùnrin ni ó fé fi s'aya ṣùgbọ́n kò gbà fún ẹnì kankan nínú wọn. Àwọn òbí rẹ ni yan ọkọ fún ṣùgbọ́n kò tẹ́lẹ̀ ẹniti wọn yan fún un.

Ní ọjọ́ kan ó ṣe alápàdé ọmọkùnrin kan tí ó rẹwà, ó sì wu ọmọbìnrin yìí dáadáa. Ó sọ fún ọmọkùnrin yìí pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ, òun sì fẹ́ kí ó jé ọkọ òun. Ọmọkùnrin yìí kọ̀ pé òun kò ní fẹ́ ọmọbìnrin yìí, ṣùgbọ́n ó fàáké kọ́rí pé ọmọkùnrin yìí ni òun ni láti fẹ́ láìmọ̀ pé sènìyàn-sẹranko ni ọkùnrin náà, erè inú omi ni, ó paradà láti wá sí ìjọ àwọn adáríhunrun lásán ni. Nígbà tí ọmọbìnrin yìí kò gbà, ni ọmọkùnrin yìí bá sọ pé òun yóò fẹ́ẹ, ó sì sọ fún ọmọbìnrin náà wí pé ilé òun jìnà,ọmọbìnrin sọ fún un pé ibikíbi tí ọmọkùnrin yìí bá ń lọ òun yóò bàa lọ.[2]

Nígbà tí wọ́n rìn díè tí wọ́n dé ibi tí àwọ̀ ọmọkùnrin yìí wà, ní ọmọkùnrin yìí bá yà sí inú igbó tí ó sì gbé àwọ̀ erè rẹ̀ wọ̀. Bí erè ti fà dé ojú ọ̀nà ni ó fa Ẹsẹ̀ ọmọbìnrin yìí ṣe rí ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ yìí ni ó bá f'ariwo ta pẹ̀lú orin lẹ́nu báyìí pé:

Orin Ààlọ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọmọbìnrin: - - - - - - - - - -Nìkún o, Nìkún ninì

Ègbè: - - - - - - - - - - Ninini, Nìkún ninì

Ọmọbìnrin: - - - - - - - - - - - Nìkún o, Nìkún ninì

Ègbè: - - - - - - - - - - - Ninini, Nìkún ninì

Ọmọbìnrin: - - - - - - - - - - --bàbá fi mí f'ọkọ ẹ̀mí ò gbọ́ o

Ègbè: - - - - - - - - - - Ninini, Nìkún ninì

Ọmọbìnrin: - - - - - - - - - - ìyá fi mí f'ọkọ ẹ̀mí ò gbà o

Ègbè: - - - - - - - - - - Ninini, Nìkún ninì

Ọmọbìnrin: - - - - - - -ọkọ nìkan tí mo fẹ́ ló bá derè o

Ègbè: - - - - - - - - Ninini, Nìkún ninì

Ọmọbìnrin: - - - - - - Nìkún o, Nìkún ninì

Ègbè: - - - - - - - - Ninini, Nìkún ninì

Bí ọmọbìnrin yìí ṣe ń kọ orin ni erè bẹ̀rẹ̀ sí gbéemi díè díẹ̀. Ṣé orí tí yóò sunwọ̀n nigb'aláwò re ko ni, ọkàn nínú àwọn ọmọkùnrin tí wọ́n tí k'ọnu sí obìnrin yìí láti fi s'aya wà lórí ẹ̀gùn tí ó ń s'ọdẹ. Bí ó ti gbé ojú wo iwájú ni ó rí erè tí ó ń gbé ọmọbìnrin yìí mì. Bí ọkùnrin yìí ṣe ta ìbọn mọ́ erè nìyí tí erè sí kú lẹ́yìn èyí ni ọmọbìnrin náà yọ jáde l'ẹnu erè[3][4].

Ẹ̀kọ́ Inú Ààlọ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ààlọ́ yìí kọ́ wa pé kò yẹ kí á máa ṣe àìgbọràn sí àṣẹ àwọn òbí wa. Kí á sì tún má máa ṣe fáàri àṣejù.

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. https://www.scribd.com/book/325976572/Yoruba-Folk-Tales
  2. https://yorubafolktales.wordpress.com/
  3. https://ng.loozap.com/ads/akojopo-alo-ijapa-apa-kini/19079098.html[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  4. https://dokumen.tips/documents/akojopo-alo-ijapa-babalola?page=80

Ẹ̀ka:Aalo, Yoruba Folklores