Abiodun Koya

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Abiodun Koya
Ọjọ́ìbíọjọ́ kejìlélólógún Oṣu kejìlá ọdún 1980
Ọmọ orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Iṣẹ́akọrin, akewi, òṣèré, ònkọ̀wé

Abiodun (Abi) Koya (A bí ní ọjọ́ kejìlélólógún Oṣu kejìlá ọdún 1980) ó jẹ́ ọmọ abínibí ìlú Nàijíríà, ó jẹ́ olórin aláìlẹ́gbẹ́, akọrin, akewi, òṣèré, ònkọ̀wé ati onínúrere tí ó tẹ̀dó sí ìlú Amẹrika.[1]

Ó jẹ́ ọkán nínú awọ́n ọ̀jọ̀gbọ́n akọrin tín se abínibí ìlú Áfíríkà tó gba ẹ̀kọ́ orin aláìlẹ́gbẹ́. Wọ́n pèé ni akọrin àwọn àarẹ àti Ọba. Abiodun Koya tí korin ní White House, níbi àwọn ìfíníjóyè àarẹ ati ni Apejọ National Democratic. A bíi ní Ìpínlẹ̀ Ògùn ti Nàijíríà, bàbá rẹ̀ gbàá níyànjú lórí orin nípa ṣíṣe àfíhàn orin aláìlẹ́gbẹ́ fun u ní ọmọ ọdún mẹ́ta, Koya nifẹ sí orin nígbàtí ó di ọmọ ọdún mẹ́fà, ó ma ń ta violin, ó sì maa n kọrin aláìlẹ́gbẹ́ ní ilé ijọsin. Ó kúrò ní ìlú Nàijíríà ní ọdun 2001 lọ sí Amẹrika níbití ó ti kẹkọọ Ìṣàkóso Ìṣòwò ní Ilé-ẹkọ́ gíga District of Columbia, Washington, DC. Ó tẹ̀síwájú láti kọ́ ẹ̀kọ́ orin fún àléfà óyè rẹ̀ ní Ilé-ẹkọ́ gíga Kátólíkì, Washington. DC [2] [3]

Nígbàtí ó n kọrin fún diẹ nínú àwọn ólùdarí gbajúgbajà àgbáyé ní òde òní, á ti ṣe àpèjúwe rẹ̀ bi ọ̀kan nínú àwọn ohùn tí ó dára jùlọ ní àgbáyé. Ó ti kọrin káàkiri àgbáyé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ólùdarí àgbáyé pẹ̀lú àwọn àarẹ ati ọba, àwọn íkọ̀, ati àwọn ọmọ ilé-ìgbìmọ̀ ijọ́bá. Ní ọdún 2009 ó ṣe àgbéjáde àkjopọ̀ tí àwọn éwì ìfẹ́ rẹ̀ tí a pè ní "Ìṣesí Ọmọ ọba-bìnrin". Koya jẹ́ olórí Àjọ ẹ̀bùn, ó sì maa n ṣe àwọn iṣẹ́ ìtọ́ni. Àjọ ẹ̀bùn rẹ̀ n pèse àwọn síkọ́láshípù fún àwọn ọmọbìrin ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ́-èdè Áfíríkà[4][5][6][7]

Àwọn Ìtọ́ka Sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Our Yoruba movies turn me off – Abiodun Koya". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2017-04-30. Retrieved 2022-07-26. 
  2. Group, Edward Sylvan, CEO of Sycamore Entertainment (2022-01-16). "Rising Star Abiodun Koya On The Five Things You Need To Shine In The Music Industry". Authority Magazine (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-04-19. 
  3. Cliche (2021-12-29). "Cliché Interview with Nigerian-Born Classical Singer Abiodun Koya". Digital Online Fashion Magazine | Free Fashion Magazine | Fashion Magazine Online (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-04-19. 
  4. "Our Yoruba movies turn me off – Abiodun Koya". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2017-04-30. Retrieved 2022-04-19. 
  5. "About Us - Abiodun Koya Foundation". abiodunkoyafoundation.org. Retrieved 2022-04-19. 
  6. Ladybrille.com (2008-05-15). "Africa's Opera Divas, Chinwe Enu & Abiodun Koya ~ Ladybrille® Blogazine". Africa's Opera Divas, Chinwe Enu & Abiodun Koya ~ Ladybrille® Blogazine. Retrieved 2022-04-19. 
  7. "Best Bobby Jones Gospel Moments: Season 35, Episode 5". BET (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-04-19.