Anastasios George Leventis
Anastasios George Leventis | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | December 1902 Lemythou, Cyprus |
Aláìsí | October 25, 1978 |
Iṣẹ́ | Entrepreneur, founder and owner of Leventis Group |
Anastasios George Leventis (Gíríkì: Αναστάσιος Γ. Λεβέντης; December 1902 – October 25, 1978) Jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gíríkì tí ó jẹ́ olùṣòwò tí ó dá onírúurú ilé iṣẹ́ kalẹ̀ jáàkiri àgbáyé, pàá pàá jùlọ ilẹ̀ Adúláwọ̀ tí ó fi kan orílẹ̀ èdè . Nàìjíríà, ìyẹn Leventis (Nigeria) Plc, tí ọba Aláké ti ilẹ̀ Ẹ̀gbá oba Ladapo Ademola sì fi jẹ oyè Bàbáláje ilẹ̀ Ẹ̀gbá.
Ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo tí ó jẹ́ bẹ́rẹ̀ fun tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Fotini ni ó fẹ́ olóṣèlú kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tassos Papadopoulos, tí ó fìgbà kan jẹ́ Ààrẹ́ orílẹ̀-èdè Cyprus tẹ́lẹ̀ rí
Ìgbé ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Leventis ní abúlé Lemythou, ní ìletò Limassol District, ní ìlú Troodos Mountains. Bàba rẹ̀ jẹ́ Mínísítà fún ilé ìjọsìnn Greek Orthodox Church tí ó sì tún jẹ́ olùkọ́ nílé ìjọsìn kan náà.[1]Leventis lọ sí ilé -ẹ̀kọ́ Mitsis Commercial School nígbà tí ó pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16), ó ṣàtìpó lọ sí ilẹ̀ Farasé láti lọ wá iṣẹ́ àtí láti ẹkẹ́kọ̀ọ́. Ní ọdún 1920, ó rí ànfàní láti ṣiṣẹ́ ní ilẹ̀ Nàìjíríà gẹgẹ́ bí ọlọ́jà ní Nwaniba, lópòópónà Cross River.
Ìgbòkè-gbodò iṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọdún 1922, Leventis dara pọ̀ mọ́ iké iṣẹ́ A.J. Tangalakis ní Abeokuta, ìpínlẹ̀ Ogun. Ó ní ìbáṣepọ̀ tó lọ́ọ̀rìn pẹ̀lú àwọn ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà nígbà tí ó ń ṣiṣẹ́ ní Abẹ́òkúta. Nígbà tí ó ìbáṣepọ̀ rẹ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀ tán pẹ̀lú ọ̀gbẹ́ni G.B. Ollivant, Leventis ṣiṣẹ́ pẹ̀lú iké iṣẹ́ aládàpọ̀ títí ó fi di adarí àgbà fún ilé iṣẹ́ G. B. Ollivant tí ó wà ní orílẹ̀ èdè Ghana.[2] Ní ọdún1937, ó kúrò nílé iṣẹ́ náà lẹ́yìn tí United Africa Company ra ilé iṣẹ́ náà. Lẹ́yìn èyí,,Leventis lọ dá ilé iṣẹ́ tirẹ̀ kalẹ̀, tí ó sì ń ra ọjà tí ilé iṣẹ́ kan bá ti ṣe jáde fún títà, tí ó sì ń rí ìrànlọ́wọ́ owó láti ọwọ́ ọ̀dọ̀ àwọn "British cotton manufacturers". Bákan náà ni ó tún rí ìraànwọ́ owó lọ́wọ́ ọmọ iyá rẹ̀ kan tí ó ń jẹ́ C.P. Leventis, ẹni tí ó dá ẹ̀ka ti ilẹ̀ Nàìjíríà kalẹ̀ ní ọdún1942, pẹ̀lú orẹ̀ rẹ̀ G.E. Keralakis. Bí orílẹ̀ èdè Ghana, Leventis káànú àwọn ajìjà-ǹ-gbara tí wọ́n jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Ghana. Òun àti Kwame Nkrumah àti J.B. Danquah jé ọ̀rẹ́. Nígbà tí rògbòdìyàn bá ṣẹlẹ̀, láàrín ìlú, ọ̀pọ ilé-ìtajà àwọn àtọ̀ún-rìnwá ni wọ́n ma ń tì pa tàbí kí wọ́n sún wọ́n níná àyàfi ti ọ̀gbẹ́ni Lẹ́vẹ́ntíìsìì ni wọ́n ma ń yọ̀ǹda fún láti tajà ní gbogbo àsìkò náà. Wọ́n fi ṣe Aṣojú orílẹ̀-èdè Ghana sí orílẹ̀-èdè Faran nígbà tí Nkrumah di Ààrẹ orílẹ̀-èdè Ghana.
Ní ọdún1940, ilé iṣẹ́ rẹ̀ dojú kọ àwọn ìṣòrọo kan, ìjọba ilẹ̀ UK fòté lé iye ẹ̀gbọ̀n òwú rí ó le wọlé láti ilẹ̀ Adúláwọ̀ léte àti dá sí okòwò aṣọ àti epo-rọ̀bì àríwá ilẹ̀ Adúláwọ̀, lẹ́yìn ìparí ogun àgbáyé ẹlẹ́kejì "World War II" , wọn kọ̀ rí ọjà rà tábí tà mọ́, ìpèníjà wọ̀nyí mú ìfàsẹ́yìn vá iṣẹ́ A.G Leventis láyi nàyẹ́ rẹ̀ tán nílẹ̀ Nàìjíríà, tí ó lè ní A.G. Leventis Nigeria Plc. Láàrín ọdún díẹ̀, okòwò ilẹ̀ Nàìjíríà yí bírí kúrò lórí okòwò ẹ̀gbọ̀n owú sí òwò kátà-kárà pẹ̀lú oríṣiríṣi ọjà. Níparí ọdún 1940, ilé-iṣẹ́ náà pàwọ̀dà látàrí àyípadà òwò lásìkò yí. Ní ọdún 1960, ìjọba ilẹ̀n Nàìjíríà gbéṣé ìkọ́lé ìtura kànkà kan fún ilé-iṣẹ́ àkójọpọ̀ Leventis pé kí ó kọ́ ilé ìtura àpapọ̀ ti ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ìyẹn "Federal Palace Hotel" gẹ́gẹ́ bí ìjọba ilẹ̀ Nàìjíríà ṣe bèrè fun. Ilé ìtura náà dúró fún ilé ìgbé àwọn ará ikẹ̀ òkèrè lásìkò ayẹyẹ òmìnira ẹ̀ Nàìjíríà. Nígbà tí ó di ọdún 1960, ilé-iṣẹ́ rẹ̀ ti gbèrú sókè tíó sì di ọ̀kan gbòógì lára àwọn ilé iṣẹ́ ìtajà ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó gbìyàǹjú láti yí ilé iṣẹ́ rẹ̀ padà kúrò ní ilé ìtajà lásán padà sí ilé iṣẹ́ àkànṣe àti ìkópamọ́ àwọn ọjà pàtàkì. Ní àsìkò yí, ilé iṣẹ́ rẹ̀ gbẹrú si látàrí àyípadà tí ó débá okòwò ilẹ̀ Nàìjíríà, àti bí àwọn ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà tí wọ́n jé ajìjà-ǹ-gbara fún òmìnira ilẹ̀ Nàìjíríà ṣe jókòó lé iṣẹ́ òwò ṣíṣe nílẹ̀ baba wọn ní àsìkò ọdún 1970. Èyí ló fún Lẹ́vẹ́ntíìsì láǹfàní láti jẹ́ kí àwọn iní bàárà ré àtibàwọn ènìyàn míràn óbtún fẹ́ràn rẹ̀ sii látàrí bí ó ṣe ń fa ojú wọn mọ́ra nípa títajà lówó pọ́ọ́kú fún wọn. Yàtọ̀ sí èyí, ó tú tún ṣe ìkúnlápá fún ègbẹ́bàwọn ajìjà-n-gbara nílẹ̀bNàìjíríà. Látàrí ìbáṣepọ̀ tó dán mọ́rán tí ó wà láàrín òun àti Olùṣọ́ Àgùtàn Makarios III, wọ́n fi ṣe aṣojú ilẹ̀ Cyorus aí àjọ UNESCO, tí ó sì tún gba àmì ẹ̀yẹ St. Barnabas.
Iṣẹ́ ìtọrẹ-àánú rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n dá àjọ (Leventis Foundation) ní ọdún 1979kalẹ̀ ẹ́yìn tí A.G Levetis kú ní ọdún 1978. Àjọ náà ṣe iṣẹ́ ìórẹ àánú púpọ lórúkọ rẹ̀ nípa ríra àwon àwòrán olówó iyebíye tó ṣàfihàn àṣà àti ìṣẹ̀ṣe sínú ilé ìṣura ohun àbáláyé ilẹ̀ Cyprus, Greec àti ọ̀pọ̀ ilé ìṣura lágbàáyé lápapọ̀fún àǹfàní àwọn knìwàádìí ìmọ̀. Àjọ yí tún ń ṣagbátẹrù fún àwọn ohun tí ó jẹ mọ́ àṣà , bẹ́ẹ̀ náà ni ó tún ń pèsè ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ti kẹ̀kọ̀ọ́ gboye kúrò ní Fàsitì àmọ́ tí wọ́n ṣì ń ṣe iṣẹ́ ìwádí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìmọ̀ akiọ́lọ́jì àti ìmọ̀ iṣẹ́ àgbẹ̀..[3] Bákan náà ni àjọ yí tú ṣe ìkúnlápá fú ìmọ̀ ìwádìí nípa ààbò áwùjọ àti ìwádí nípa iṣẹ́ ìlera.[4]
Ní ọdún 1987 wọ́n fi àwòrán A.G. Leventis lọ́lẹ̀ ní àwọn ilé ìpamọ́ ìṣura : British Museum, [5] ti Fitzwilliam Museum ní 1997 àti ti Metropolitan Museum of Art New York ní 2000.
Ní ọdún 2008 wọ́n fi A.G. Leventis je ọ̀jọ̀gbọ́n àgbà ní ilé ẹ̀kọ́ Cambridge University ní Greek culture nígbà tí wọ́n oèé ní ọ̀jọ̀gbọ́n àṣà A. G. Leventis Professor of Greek Culture.[6]
Ìgbésí ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]A lè tọpasẹ̀ ìran rẹ̀ padà sí ọ̀rùndún kejìdínlógún (28th century). Nígbà tí baba ńlá rẹ̀ ṣàtìpó lọ sí Peloponnese gẹ́gẹ́ bí ìtàn 'Olov' ṣe gbe ní 1770. Nígbà tí wọ́n fẹ́ bi, ọ̀pọ̀ àwọn Biṣọ́ọ̀bù tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ ilé ìjọsìn Othodox ti Jerusálẹ́mù àti Antioch, àti àwọn alàgbà ilé ìjọsìn as Cyprus.
Wọ́n bi ní oṣù Kejìlá ọdún 1902 ní ìlú Lemythou, ní orílẹ̀ èdè Cyprus. Bàbá àti ìyá rẹ̀ ni : Neoklis/Papaneoklis Leventis àti Salome Theocharides, ó ní ọ̀pọ̀lọpọ àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò lọ́kùnri àti lóbìnri, lára wọn ni: Costas; George, ẹni tí ó kọ́kọ́ lọ sí ilẹ̀ Íjípítì; Kalliopi, tí wọ́n pè oùn náà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó gbé eré Alki David; Evagoras; Katerina, tí ó sì tún fẹ́ ọ̀gbẹ́ni Myrianthousis; Charalambos; Anastasios; Christodoulos; àtiDavid.
Lẹ́vẹ́ntíìsì fẹ́ Maria Fotini, lẹ́ni tí ó bí ọọmọ kan ṣoṣo fun ìyẹn Papadopoulos Leventis.
Bákan náà ni ó tún jẹ́ àbúrò bàbá fún Constantine (Dino) Leventis (1938–2002), olùṣòwò tí ó jẹ ànfàní lọ́pọọ̀ nínú àwòrán Hellenic art ní (Metropolitan Museum of Art in New York) àti àwọn ilé ìṣura ohun àbáláyé káàkiri àgbáyé. Ní April 2000, ilé ìṣura Metropolitan ṣí àjọ A.G. Leventis ìyẹn (Foundation Gallery) níbi tí ọ̀pọ̀ ihun ìṣura àbáláyé bí ère Cypriot, terracottas, vases, jewelry àti coins tí a lè tọpasẹ̀ rẹ̀ padà sí ọ̀rùndún kẹrin àti ọ̀rùndún karùún ṣájú kí wọ́n tó bí Jésù. Àjọ náà tún ṣèrànwọ́ nípa sísan owó fún àwọn ihun ìṣura ti ó jẹ mọ́ ilẹ̀ Gíríkì , Louvre ní ilẹ̀ Paris àti ilé ìṣura Fitzwilliam tí ó wà ní ilé ẹ̀kọ́ àgbà Cambridge University, àti àwọn mìíràn gẹ́gẹ́ bí ìjábọ̀ ọdọdún wọn ti wí. Ní ilẹ̀ Greece, àjọ náà ti náwó lọ́pọ̀lọpọ̀ sórí iṣẹ́ akíọ́lọ́jì tó pọ̀brẹpẹtẹ.
Àwọn ìtọ́ka sí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Supplement on A.G. Leventis". New Nigerian. December 19, 1978.
- ↑ Empty citation (help)
- ↑ "Foundation awards scholarships to 27 post-graduates". Ghana News Agency. November 30, 2013. http://www.ghananewsagency.org/education/foundation-awards-scholarships-to-27-post-graduates--67940. Retrieved 26 May 2014.
- ↑ Empty citation (help)
- ↑ Arapoglu, Evita (1994). The A.G. Leventis Collection : 19th-20th century Greek paintings : 4-30 November 1994.. London: Hellenic Center. http://www.worldcat.org/title/ag-leventis-collection-19th-20th-century-greek-paintings-4-30-november-1994/oclc/078241324.
- ↑ "New chair in Ancient Greek culture established". University of Cambridge News. October 7, 2008. http://www.cam.ac.uk/news/new-chair-in-ancient-greek-culture-established. Retrieved 26 May 2014.