Augustine Ukattah

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Augustine Ukattah (tí wọ́n bí ní August 28,1918, tó sì ṣaláìsí ní January 27,1996) je oluko ile Naijiria ati oloselu.

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Augustine Echewodor Ukattah ní Ahaba-Oloko ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Ikwuano ní Ìpínlẹ̀ Ábíá, ní August 28, 1918.[1] Ukattah jẹ́ ọmọkùnrin kẹrin tí Ukattah Nkor Abajuo àti Ejighiato Nwamgbede Ukattah, bí. Àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì jẹ́ Ahaba-Oloko. Bàbá rè kú nígbà tó ṣì kéré, tí ó sì ń gbé lọ́dọ̀ àbúrò bàbá rè, ìyẹn Chief Mathew Ugoani. Ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Christ the King ní Aba ló lọ, àti ilé-ìwé St. Theresa ní Okigwe. Lẹ́yìn iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gé bí olùkọ́ àwọn akẹ́kọ̀ó, ó lọ sí St. Charles Teacher Training CollegeOnitsha,[2] ní ọdún 1941. Ó yege gẹ́gẹ́ bí i Higher Elementary Teacher ní ọdún 1944, ó sì ṣàṣeyege nínú ìdànwó ti àwọn olùkọ́ àgbà nínú ẹ̀kọ́ ìtà, ní ọdún1948.

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Who's who in Nigeria. Nigerian Printing and Publishing Company. 1958. p. 264. https://books.google.com/books?id=egUaAAAAIAAJ&q=Augustine+Ukattah. Retrieved 6 April 2015. "UKATTAH, Augustine Echewodor, M.H.R. teacher; b. 28 August 1921; ..." 
  2. Legislators of Eastern Nigeria. Eastern Nigeria Information Service. 1958. p. 51. https://books.google.com/books?id=zfY2AAAAIAAJ&q=A+E+Ukattah. Retrieved 6 April 2015. "A. E. UKATTAH, BENDE: Age 36; educated at St. Charles' College, Onitsha. ..."