Awa Sène Sarr

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Awa Sène Sarr
Orílẹ̀-èdèSenegalese
Iṣẹ́Actress
Ìgbà iṣẹ́1989-present

Awa Sène Sarr jẹ́ òṣèrébìnrin àti apanilẹ́ẹ̀rín ọmọ orílẹ̀-èdè Sẹ̀nẹ̀gàl.

Isẹmi rẹ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Awa Sène Sarr lẹnìkan tí ó ní ìfẹ́ sí láti di amòfin tó sì ṣe bẹ́è kẹ́kọ̀ọ́ òfin ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásitì ìlú Dakar. Lẹ́hìn náà ó forúkọsílẹ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ eré ṣíṣe ní National Institute of Arts of Dakar ní orílẹ̀-èdè Sẹ̀nẹ̀gàl, ó sì gboyè ní ọdún 1980.[1]

Sarr ti kópa nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ayẹyẹ àjọ̀dún fíìmù tó fi mọ́ ti Cannes ní ọdún 2005.[2] Ní ọdún 2000, ó kó ipa gẹ́gẹ́ bi Mada nínu eré Ousmane Sembène kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Faat Kiné.[3]

Sarr ti kópa nínu àwọn eré tó lé ní ogójì, tó fi mọ́ eré tí àwọn ònkọ̀tàn bíi Marie N'Diaye, Ahmadou Kourouma, Catherine Anne àti Philippe Blasband kọ.[4] Ó maá n ṣe olóòtú ètò Horlonge du Sud literary café ní gbogbo oṣooṣù ní Ìlú Brussels, léte láti gbé àṣà ilẹ̀ Áfíríkà lárugẹ.[5]

Ó ṣe atọ́kùn ètò rédíò kan tó dá lóri ewì èdè Wolof tí àkọ́lé rẹ̀ n jẹ́ Taalifi Doomi Réewmi lóri ìkànnì rédíò Radiodiffusion Télévision Sénégalaise (RTS).[6]

Sarr ti kó ipa gẹ́gẹ́ bi àjẹ́ kan nínu àwọn fíìmù mẹ́ta ti Michel Ocelot. Àwọn fíìmù náà ni Kirikou and the Sorceress (1998), Kirikou and the Wild Beasts (2005), ati Kirikou and the Men and Women (2012).[7]

Àwọn àṣàyàn eré rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • 1989 : Dakar Clando
  • 1989 : Le grotto de Sou Jacob
  • 1997 : Une couleur café d'Henri Duparc
  • 1998 : Kirikou and the Sorceress
  • 2000 : Faat Kiné
  • 2000 : Amul Yakaar
  • 2000 : Battù
  • 2005 : Kirikou and the Wild Beasts
  • 2012 : Kirikou and the Men and Women

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Awa Sène Sarr". Africultures (in French). Retrieved 6 October 2020. 
  2. "Awa Sène Sarr". Africultures (in French). Retrieved 6 October 2020. 
  3. "FILM REVIEW; At a Gas Station, Finding the Answers to Life's Questions". https://www.nytimes.com/2001/03/28/movies/film-review-at-a-gas-station-finding-the-answers-to-life-s-questions.html. Retrieved 6 October 2020. 
  4. "Awa Sène Sarr". Africultures (in French). Retrieved 6 October 2020. 
  5. "Awa Sène Sarr dans Bruxelles revit : de la littérature africaine aux “masques pour tous”". BX1 (in French). 11 June 2020. Retrieved 6 October 2020. 
  6. "Awa Sène Sarr". Africultures (in French). Retrieved 6 October 2020. 
  7. "Awa Sene Sarr". RFI (in French). 6 April 2017. Retrieved 6 October 2020. 

Àwọn ìtakùn Ìjásóde[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]