Ayoola Akinwole

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Professor_Ayoola_Akinwole

Professor of Aquaculture and Water Resources Management


Wọ́n bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Ayọ̀ọlá Olúṣẹ́gun Akínwọlé ní ọjọ́ kẹfà, Oṣù Okúdù Ọdún 1969 sí ẹbí Akínwọlé ti ìdílé Akínàjó ní ìlú Ìbàdàn, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Orílẹ̀èdè [[Nàìjíríà.

Ètò ẹ̀kọ́ ati iṣẹ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ayọ̀ọlá lọ sí Yunifásítì Iṣẹ́ Àgbẹ̀ ti Ìlú Abẹ́òkúta, - University of Agriculture) , Abẹ́òkúta níbi tí ó ti gba oyè B.Sc nínú Ìbáṣepọ̀ Iṣẹ́ àgbẹ̀ òun ojú ọjọ́ àti ìṣàkóso omi (Agricultural Meteorology and Water Management) gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́ tó peregedé julọ̀ ní ọdún 1994. Ó gba oyè M.Sc nínú Ìmọ̀ - Ẹ̀rọ̀ Iṣẹ́ Àgbẹ̀ (Agricultural Engineering) ní ọdún 1999 ní Yunifásítì ti Ìlú Ìbàdàn [1] tí ó sì yan Ìmọ̀ ẹ̀rọ nípa ìsọlọ́jọ iyẹ̀pẹ̀ àti omi láàyò .


Ó gba oyè Ọ̀mọwé (Ph.D) nínú  Ìṣẹ̀dá inú omi àti Ìmọ̀ nípa ìtọ́jú ẹja ní ọdún 2005 ní Yunifásítì ti Ìlú Ìbàdàn.

Ó darapọ̀ gẹ́gẹ́ bí Amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ olùkọ́ ní ẹ̀ká - ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ ẹranko inú-igbó àti ìtọ́jú ẹja (Department of Wildlife and Fisheries Management) ní ọjọ́ kìn-ìn-ín Oṣù Ògún, Ọdún 2000. Ó ń gba ìgbéga ní ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀lẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ títí tí ó fi di Ọ̀jọ̀gbọ́n akọ́sẹ́mọṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ nínú iṣẹ́ àgbẹ̀ ní oṣù Òwàrà ọdún 2014. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹgbẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Akínwọlé ti jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́, nílé àti lókè-òkun.

Ọmọ Ẹgbẹ́ Ẹ̀ka ìmọ̀ nípa Ìtọ́jú ẹja ni, òun sì ni ọmọ ẹgbẹ́ akọ́sẹ́mọṣẹ́ àkọ́kọ́ tí Ẹgbẹ́ Ìmọ̀-ẹ̀rọ nípa ìṣẹ̀dá inú omi tí United States of America ó sì jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ẹ̀ká ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ nípa igbó tí orílẹ̀èdè Nàìjíríà àti àwọn ẹgbẹ́ mìíràn.

O jẹ́ asèwádìí  (Visiting Research Fellow - John D. and Catherine T. MacArthur Foundation funded Fellowship) ní ṣíṣe àtúnpìn àwọn Ìṣẹ̀dá inú omi (Recirculating Aquaculture Systems) sí Yunifásítì ti Ìpínlẹ̀ Louisiana, Baton Rouge USA ní 2010.

Ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ọmọ Ẹgbẹ́ Àjùmọ̀ṣe ìwádìí lórí ìjìnlẹ̀ ètò ìṣẹ̀dá inú omi ní ìlú àti àwọn ìgbèríko ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà(Team member on Intensive Urban and Peri-Urban Aquaculture Production Systems in Nigeria) pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ibùdó-ìmọ̀ Marine Resources and Ecosystem Studies, Yunifásítì Wageningen, Netherlands ní ọdún 2011. Ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ìwádìí (Facilities Design and Water Resources Engineering Expert) fún Àjọ Ìwọ-Oòrùn àti Gbùngbùn- Áfíríkà fún Ìwádìí àti ìdàgbàsókè iṣẹ́ àgbẹ̀ (CORAF/WECARD) àgbàṣe iṣẹ́ ìwádìí lórí Ìsọlọ́jọ àkójọpọ̀ ìmọ̀ ìṣẹ̀dá inú omi ajẹmọ́ omi adágún pẹ̀lú ìrẹsì àti ìpèsè ọ̀sìn ẹyẹ: Àyẹ̀wò ọ̀rọ̀ ajé, amúlùúdùn àti àyíká ní ọdún 2011 sí 2015.

Bákan náà ni ó jẹ́ Onímọ̀ ìmọ̀-ẹ̀rọ̀ iṣẹ́ àgbẹ̀ fún ìdàgbàsókè iṣẹ́ fún Báànkì Àgbáyé CORAF/WECARD lórí ìléèṣẹ́wọ̀gbẹ́ àti ìrònilágbara ní ẹsẹ̀kùkú nípasẹ̀ Ìsọlọ́jọ Àkójọpọ̀ Ìdàgbàsókè Ìṣẹ̀dá inú omi: Ẹja tòun ti ìrẹsì àti ìpèsè ọ̀sìn Ẹlẹ́dẹ̀  ní ọdún 2012 àti 2016. Àwọn iṣẹ́ wọ̀nyíí jẹmọ́ ìkọ́ra-ẹni àti ìdásílẹ̀ àwọn àkójọpọ̀ àwọn ohun èlò oko ẹja ní àwọn orílẹ̀èdè ní apá ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà ti Nàìjíríà, Cote D'Ivoire, Senegal, Sierra-Leone, Benin, Togo àti Cameroon. Ṣé Ìdásílẹ̀ ìwádìí oríṣìí méjì irú rẹ̀ àti àwọn ohun èlò ìkọ̀ṣẹ́ ní oko ẹja ní Ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Ẹ̀rọ Ẹ̀kọ́ nípa Ẹja tí Kọ́lẹ́jì Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tí Iṣẹ́ Àgbẹ̀ àti Ìmọ̀ - Ẹ̀rọ Igbó-Ọrà ní ọdún 2014 àti 2015. Èèkàn ni nínú Ẹgbẹ́ Forestry Association of Nigeria, FFAN ó gba oyè Fellow nínú ẹgbẹ́ náà.

Ó jẹ́ Alákòóso oríṣìíríṣìí àwọn ẹ̀ká ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Àgbẹ̀ àti Ìsọdọ̀tun Àwọn Ọrọ̀ Àdáyébá, Yunifásítì ti Ìbàdàn. Ọ̀jọ̀gbọ́n Akínwọlé ti gbé iṣẹ́ àpilẹ̀kọ tí kò dín ní àádọ́rùn-ún jáde ní àwọn atẹ̀wé tó gbajúmọ̀ nílé àti lókè òkun lórí iṣẹ́ oríṣìíríṣìí ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ rẹ̀.


Ọ̀jọ̀gbọ́n  Akínwọlé jẹ́ olóye ajìjàngbara òṣìṣẹ́ àti ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn tó ṣíwájú nínú ìgbìyànjú ìdásílẹ̀ àwọ́n  ẹni ìrẹ́jẹ láwùjọ, àwọn alákadá àtí ìṣàtúnṣe èto ẹ̀kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì. Ó gòkè àgbà dé ipò Alága Ẹgbẹ́ Òṣìṣẹ́ Olùkọ́ Àwọn Yunifásítì ti Ẹ̀ka Yunifásítì Ìbàdàn (Academic Staff Union of Universities - ASUU) ní Oṣù Èrèlé, ọdún 2020 títí di àsìkò yìí.


Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Dr Ayoola Olusegun Akinwole". ‪Google Scholar‬. Retrieved 2021-09-19. 

2. https://www.researchgate.net/profile/Ayoola-Akinwole

3. https://independent.ng/ui-asuu-elects-akinwole-chairman-as-omole-bows-out/

4. https://www.sunnewsonline.com/prof-akinwole-emerges-new-ui-asuu-chair/