Ayotunde Phillips

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ayotunde Phillips
Chief Judge of Lagos State
In office
June 2012 – July 2014
AsíwájúInumidun Akande
Arọ́pòOluwafunmilayo Olajumoke Atilade
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí(1949-07-26)26 Oṣù Keje 1949
London

Ayotunde Phillips (tí wọ́n bí ní Oṣù kéje ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n, ọdún 1949 ) jẹ́ Agbẹjọ́rò Nàìjíríà àti olórí adájọ́ sẹ́yìn wàá rí Ìpínlè ̀ Èkó.[1][2]

Ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Ayotunde Phillips ní Oṣù kéje ọjọ́ kẹ́rìndínlọ́gbọ̀n, ọdún 1949, Ó jẹ́ àkọ́bí Olóǹgbé Adájọ́ James Oladipo Williams àti Henrietta Aina Williams, adájọ́ tó bí sí ìpínlẹ̀ Èkó. Ó lọ sí ilé-ìwé àkọ́bẹ̀rẹ́ rẹ̀ ní London kí ó tó padà wá sí Nàìjíríà pẹ̀lú ìbátan rẹ̀, Oluwafunmilayo Olajumoke Atilade. Ó ṣe WAEC rẹ̀ ní Queen's College, ní Ìpínlẹ̀ Èkó kí ó tó padà lọ sí Fáṣítì Èkó níbi tó ti gba oyè ní ètò-ọ̀fin (Law) ní ọdún kẹfà ọdún 1973. Ó parí Àgùbánirọ̀ tí ó jẹ́ ètò ọdún kan fún gbogbo àwọn tó bá pníí ẹ̀kọ́ Fáṣítì ti Nàìjíríà ní Ìpínlẹ̀ Enugu ní Ọ́fìsì ètò òfin ìjọba ní Ìpínlẹ̀ náà àti wí pé wọ́n pé è kó di Agbẹjọ́rò ìlú ní ọdún 1974.

Iṣẹ́ Òfin[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ ní 'Kehinde Sofola's Chambers' ní oṣù kọkànlá ọdún 1975, ọdún kan lẹ́hìn tí wọ́n pè é sí òfin (to bar). Ó kúrò nínú ìyẹwu náà ní oṣù kẹsán-án ọdún 1976 láti darapọ̀ mọ́ iṣẹ́ ti Ilé-iṣẹ́ Ìdàgbàsókè àti Ohun-ìní ti Ìpínlẹ̀ Èkó gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ òfin, ó sì dìde sí ipò olùdámọ̀ràn nípa òfin ní ọdún 1990, ní ọdún kan náà tí ó gba gbígbé sí Ilé-iṣẹ́ ti Ìdájọ́ níbití ó ti gba òye ipò ti Adájọ́ ilé-ẹjọ́ gíga kan ní ọdún 1994.[3] Ní oṣù keje, odun 2012, Babatunde Fashola yan an gege bi adajo agba, lẹ́hìn ìfẹ̀yìntì iṣẹ́ rẹ̀ ní oṣù kẹfà ọdún 2014, Adájọ́ Oluwafunmilayo Olajumoke Atilade, àbúrò rẹ̀ ló gba ipò rẹ̀.

Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Moral issues raised over Lagos Chief Judge’s book launch. - P.M. NEWS Nigeria". pmnewsnigeria.com. 
  2. "JUSTICE AYOTUNDE PHILLIP’s son marries baby mama". Encomium Magazine. 
  3. Our Correspondent. "New Telegraph – Lagos CJ: Historic succession of two sisters". newtelegraphonline.com. Archived from the original on 2015-05-14.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)