Ballot

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Bálọ́tì jẹ́ ohun èlò ìdìbò fún ìbò dídì tí a sì lè rí gẹ́gẹ́ bí ẹyọ pépà tàbí bọ́ọ̀lù kékeré tí wọ́n máa ń lò fún ìbò ìkọ̀kọ̀.[1] Ó sábà máa ń jẹ́ bọ́ọ̀lù kékeré (wo ìkọ̀sílẹ̀ òǹdíje) tí wọ́n fi ń ṣàkọsílẹ̀ ìpinnu tí àwọn òǹdìbò ṣe ní orílẹ̀-èdè Italy ní ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́rìndínlógún.[2]

Òǹdìbò kọ̀ọ̀kan máa ń lo bálọ́tì, àti pé wọ́n kìí pín àwọn bálọ́tì lò. Nínú àwọn ìbò tí kò le rárá, bálọ́tì kan le jẹ́ pépà lásán tí àwọn òǹdìbò máa ń kọ orúkọ àwọn aṣojú wọ́n, àmọ́ àwọn ìjọba máa ń lo àwọn àtẹ̀ẹ́lẹ̀ bálọ́tì láti dáàbò bo ìbò ìkọ̀kọ̀. Àwọn òǹdìbò máa ń di ìbò wọn sínú àpótí ní gbọ̀ngán ìdìbò.

Ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, èyí ni wọ́n máa ń sábà pè ní "Ballot papper.[3] Bálọ́tì jẹ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa ń lò fún ètò ìdìbò láàárín àwọn ìgbìmọ̀ (bíi kí ẹgbẹ́ ìdàpọ̀" máa ṣe ìdìbò" àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn).

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Ballot". Merriam-Webster. Retrieved 2012-11-07. 
  2. "Ballot | Origin and meaning of ballot by Online Etymology Dictionary". 
  3. "Ballot". Merriam-Webster Learner’s Dictionary. Retrieved 2012-11-07. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]