Birhane Dibaba

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Birhane Dibaba
Òrọ̀ ẹni
Ọjọ́ìbí11 Oṣù Kẹ̀sán 1993 (1993-09-11) (ọmọ ọdún 30)
Height1.60 m (5 ft 3 in)
Weight4kg
Sport
Orílẹ̀-èdè Ethiopia
Erẹ́ìdárayáAthletics
Event(s)Marathon

Birhane Dibaba tí a bí ní ọjọ́ kọkànlá, oṣù kẹsàn-án, ọdún 1993 jẹ́ ọmọbìnrin eléré sísá ti ọ̀nà jínjìn tó dá lórí ìdíje ti eré sísá ti ojú ọ̀nà[1][2][3].

Àṣeyọrí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọdún 2014, Dibaba kópa nínú Marathon ti Tokyo tó sì gbé ipò kejì láàárín wákàtí 2:22:30. Ní ọdún 2015, Birhane kópa nínú Marathon ti Tokyo tó sì gbé ipò àkọ́kọ́ láàárín wákàtí 2:23:15[4]. Ní ọdún 2015, Birhane ni a yàn gẹ́gẹ́ bíi ọ̀kan lára àwọn obìnrin tó yege nínú eré sísá ní ìdíje àgbáyé láti ṣojú fún ẹgbẹ́ eré sísá àwọn obìnrin ti ilẹ̀ Ethiopia[5]. Ní ọdún 2017, Birhane kópa nínú ìdíje àgbáyé ti eré sísá nínú Marathon ti àwọn obìnrin.

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Player Olympics
  2. Player Athletics Details
  3. Birhane Profile
  4. 2015 Tokyo Marathon Results
  5. 2015 World Championships