Debo Ogundoyin

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Débọ̀ Ògúndoyin jẹ́ olóṣẹlú ọmọ orílẹ̀ èdè [[Nàìjíríà]] kan. Òun ni ó jẹ́ aṣojú ẹkùn Èrúwà ní ìlà Oòrùn ìjọba ìbílẹ̀ Ìbàràpá àti agbọ̀rọ̀sọ tàbí agbẹnusọ fún ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin ẹlẹ́kẹẹ̀sán irú rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ làbẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party (PDP).[1] Wọ́n bí Débọ̀ ní ọjọ́ Kejìdínlógún oṣù Kejì ọdún 1988 (18 02, 1988), òun ni ó jẹ́ aṣòfin àti agbẹnusọ́ fún ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tí ó jẹ́ ọ̀dọ́ nínú ìtàn iké ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Ó dé ẹnu iṣẹ́ ní ọjọ́ Kẹwá oṣù Kárùnún ọdún 2019 (June 10, 2019). [2] [3]

Igbé-ayé àti Ẹ̀kọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Débọ́ wá láti Èrúwà tí ó jẹ́ ìlú kan ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Ìlà Oòrùn bàràpá ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ fásitì Babcock . [4][5]

Ẹbí rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Débọ̀ Ògúndoyin jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ Olóyè Adéṣeun Ògúndoyin tí ó jẹ́ tí ó jẹ́ oníṣòwò pàtàkì àti olójú àánú pẹ̀lú ọlọ́rẹ àtinú wá. Débọ̀ pàdánù bàbá rẹ̀ nígbà tí ó wà ní èwe ní ọdun 1991. Bàbá rẹ̀ Adéṣeun Ògúndoyin jẹ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ojúgbà rẹ̀ bíi: Alhaji Aríṣekọ́lá Àlàó Olóyè Àkàní Àlùkò ní ìgbà ayé rẹ̀ ní ìlú Ìbàdàn.[6]

Àwọn ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Debo Ogundoyin has the leadership qualities to be speaker of the house – ibarapa Youths". Latest Alert. 2019-04-14. Archived from the original on 2019-06-29. Retrieved 2019-06-29. 
  2. "Men In Their 30s Elected As Speakers In Oyo, Plateau States". Sahara Reporters. 2019-06-10. Retrieved 2019-06-29. 
  3. "Davido congratulates Oyo new Speaker, Debo Ogundoyin". P.M. News. 2019-06-11. Retrieved 2019-06-29. 
  4. "Redirect Notice". Google. Retrieved 2019-06-29. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  5. Hernandez, Dammie (2019-06-10). "Debo Ogundoyin Biography and Life History". KikioTolu News. Retrieved 2019-06-29. 
  6. "Biography of Debo Ogundoyin - Noisemakers". Latest Nigerian News Today. 2019-06-10. Archived from the original on 2019-06-16. Retrieved 2019-06-29.