Felicia Adeyoyin

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Felicia Adeyoyin
Fáìlì:Felicia Adeyoyin.png
BornỌjọ́ kẹfà oṣù kọkànlá ọdún 1938
DiedỌjọ́ kínní oṣù karùn-ún ọdún 2021
NationalityỌmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà
InstitutionsYunifásitì ìpínlè Èkó
Alma materBirkbeck University; Yunifásitì ìpínlè Èkó
Doctoral advisorJ. U. Aisiku; A. I. Asiwaju
Known forAuthor of the Nigerian national pledge
Notable awardsOrder of the Niger

Felicia Adebola Adeyoyin (tí a bí ní ọjọ́ kẹfà oṣù kọkànlá ọdún 1938 tí ó sì fi ayé sílè ní ọjọ́ kínnií oṣù karùn-ún ọdún 2021) jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n ní Yunifásítì ìlú Èkó àti ọmọ ọba ní ilé Iji ní Saki, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Òun ni ó kọ Nigerian national pledge.[1]

Ìpìlẹ̀ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Felicia Awujoola ní ọjọ́ kẹfà oṣù kọkànlá ọdún 1938 ní Ogbomoso, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.[2][3] Ó lọ Idi-Aba, ilé-ìwé Baptist kan ní Abeokuta ní àárín ọdún 1953 sí 1957.[2] NÍ ọdún 1965, ó fẹ́ Solomon Adedeji Adeyoyin, ẹni tí ó kàwé ní ilé ìwé Idi-Aba's fún àwọn ọkùnrin.[3][2]

Ẹ̀kọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Felicia gba àmì-ẹ̀yẹ Bachelor Degree nínú ìmò Jiografi ní Birkbeck, Yunifásitì London ní ọdún 1968 àti àmì-ẹ̀yẹ Diploma of Education ní Yunifásitì kan náà ní ọdún 1976,[4] kí ó tó gba àmì-ẹ̀yẹ M.A. nínú ìmò Social Studies ní Columbia University ti ìlú New York ní ọdún 1977, kí ó tó gba àmì-ẹ̀yẹ PhD rẹ̀ ní ọdún 1981 ní Yunifásítì ìlú Èkó.[5][6]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Nigeria @ 59: Interesting facts about Nigeria's National anthem, Pledge". The Nation (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-10-01. Retrieved 2021-05-06. 
  2. 2.0 2.1 2.2 Lawoyin, Oyeronke Alake (2007) (in en). IDI-ABA. Xulon Press. ISBN 978-1-60477-072-8. https://books.google.com/books?id=xtNp2lUM8KUC&q=Felicia+Adeyoyin&pg=PA127. 
  3. 3.0 3.1 (in en) Who's who in Nigeria. Newswatch. 1990. ISBN 978-978-2704-12-2. https://books.google.com/books?id=eq8ZAAAAYAAJ&q=felicia+adeyoyin. 
  4. "Notable Birkbeckians: Graduates In Academia". bbk.ac.uk. Birkbeck, University of London. 2021. Retrieved 2021-05-10. 
  5. "Author Of Nigeria's National Pledge, Felicia Adedoyin, Is Dead". Gistmaster (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-05-05. Archived from the original on 2021-05-05. Retrieved 2021-05-06. 
  6. Adeyoyin, Felicia (1977). "The Dynamics of Teaching Social Studies at the Grade Two Teachers' College Level in Lagos State" (PDF). [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]