Foluke Adeboye

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Foluke Adeboye
Image of Foluke Adeboye
Ọjọ́ìbíFoluke Adenike Adeyokunnu
Oṣù Keje 13, 1948 (1948-07-13) (ọmọ ọdún 75)
Ọwá Obòkun Oji ní Ìjẹ̀ṣà, Ìpínlẹ̀ Òṣun.
Olólùfẹ́Enoch Adejare Adeboye
Àwọn ọmọmẹ́rin
WebsiteOfficial website

Foluke Adenike Adeboye jẹ́ ọmọ bíbí Jacob Adelusi Adeyokunnu, tí wọ́n bí ní ọjọ́ Ìsẹ́gun,oṣù kèje, odún 1948. Ó ma jẹyọ pé Bàbá Foluke(Jacob Adeyokunnu), ó jẹ́ ọmokùnrin àkọ́kọ́ bàbá ti ẹ̀, tí ó sì tan mọ́ ìdílé oyè, Ọwá Obòkun Oji, ti ilẹ̀ Ìjèṣà. Èyí fi hàn pé ọmọọba ni Foluke jẹ́. Olùkọ́ ìwé àti olùkọ́ ẹ̀sìn kìrìtíẹ́nì onílànà-ìdáhùn-àti-ìṣèbéèrè ni bàbá Foluke jẹ́.[1]

A tún mọ Foluke gẹ́gẹ́ bí i Mummy G.O. olùṣọ́-àgùntàn ni ó jẹ́, ajíhìnrere lórí ẹ̀rọ amóhùnwáwòrán, agbọ̀rọ̀sọ ní ibi àpèjọ, òǹkọ̀wé, àti aya Enoch Adejare Adeboye, tí ó jẹ́ alábójútó gbogbogbò ìjọ Redeemed Christian Church of God.[2]

Ìwé-kíkà[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ilé-ìwé alákọ̀óbẹ̀rẹ̀ Methodist-Oke Eshe-Iléṣà, àti Methodist Girls School- Agurodo-Iléṣà ni Foluke ti kàwé, kí ó tó lọ ìwé-ẹ̀rí olùkọ́ ti ipele II ní United Missionary College-Ìbàdàn, àti ìwé-ẹ̀rí nípa ẹ̀kó( Ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ àti Ìṣirò) ní Kọ́lẹ̀èjì ti Ẹ̀kọ́, Yunifásítì ìlú Èkó.[3]

Àwon Ìtọkasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìkọ kedere

  1. "The Official Website of Pastor Foluke Adenike Adeboye". The Official Website of Pastor Foluke Adenike Adeboye. 1948-07-13. Retrieved 2022-05-22. 
  2. "Foluke Adeboye". Wikipedia. 2021-02-16. Retrieved 2022-05-22. 
  3. "Foluke Adeboye". Wikipedia. 2021-02-16. Retrieved 2022-05-22.