Jump to content

Ida S. Scudder

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ida S. Scudder gẹ́gẹ́ bi ọdọmobinrin

Dr. Ida Sophia Scudder (Ọjọ́ kẹsan oṣù kejìlá ọdún 1870 si ọjọ kẹta-lé-lógún oṣù karun ọdún 1960) jẹ ìran kẹta àwon ajínhìnrere oníwòsàn lati ilẹ India ti a n pe ni Reformed Church in America. O fi aye rẹ jin fun gbígba àwon obìnrin ilẹ̀ India kuro ninu ìpọ́njú ati gbígbógun ti àwon àrùn bi buboniki, oní'gbá-méjì àti ẹ̀tẹ̀.[1] Ni ọdun 1918, o bẹrẹ ilé ìwòsàn ti a ti nkọni ni agbègbè Asia, eyini ni, Christian Medical College & Hospital, ni adugbo Vellore, ni ilẹ India.[2]