Idia

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ère orí olorì Idia, òkan lára àwọn ère mẹ́rin nígbà ayé rẹ̀ tí ó wà ní (Ethnological Museum ti Berlin)

Idia ni ìyá Esigie, ẹni tí ó jẹ́ Oba àwọn ènìyàn Edo láàrin ọdún 1504 sí 1550.[1][2] Àwọn onítàn mọ̀ pé Idia wà láyé nígbà Ogun Idah(ogun náà wáyé láàrin ọdún 1515 sí 1516) nítorí ó kópa ribiribi láti mú ìṣẹ́gun Benin wáyé.[2] Ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì gbàgbọ́ pé, òun ni igi lẹ́yìn ọgbà bí ọmọ rẹ̀ ṣe dé orí ìtẹ́.[2] Ó jẹ́ akíkanjú tó jà gidigidi nígbà kí ọmọ rẹ̀ tó dé orí ìtẹ́ àti lẹ́yìn ìgbà tí ó di ọba Edo.[3] Ó ran ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ láti di ọba lẹ́yìn ìgbà tí Baba rẹ̀ Oba Ozolua fi ayé sílè. Ó kó àwọn ajagun jọ láti bá arákùnrin Esigie, ẹni tí a mọ̀ sí Arhuaran jà. Arhuaran ni ẹni tí ó yẹ kó di Ọba ṣùgbọ́n wọ́n ségun rẹ̀. Idah di ìyá Oba kẹrindínlógún ti Benin.[4][5]

Idia dé Àfin torí Ozolua, ẹni tí ó jẹ́ ọba láàrin 1483 sí 1514, Ozolua pinu láti fi saya lẹ́yìn ìgbà tí ó ri kó jó.[2] Idia àti Oba Ozolua fẹ́ ara wọn kí ó tó di ọdun 1504, ṣùgbọ́n àwọn onítàn ò ní ìdánilójú ìgbà tí wọ́n fẹ́ ara wọn.[2] Nítorí ìpinnu ọba, àwọn òbí Idia pèsè rẹ̀ fún ìgbé ayé rẹ̀ ní ààfin nípa fífún ní àwọn àgbo kọ̀kan.[2]

Àwọn Ìtókasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Queen Idia, Role Model,Warrior, Prominent Nigerian, Nigeria Personality Profiles". www.nigeriagalleria.com. Retrieved 2022-08-27. 
  2. 2.0 2.1 2.2 2.3 2.4 2.5 Mbow, Babacar; Ẹbọhọn, Ọsẹmwegie (2005). Benin, A Kingdom in Bronze: The Royal Court Art. Ft. Lauderdale, FL.: African American Research Library and Cultural Center, Broward County Library. ISBN 0-9772041-0-3. OCLC 62534476. https://www.worldcat.org/oclc/62534476. 
  3. Historical Dictionary of Nigeria by Toyin Falola, Ann Genova, p.160
  4. Egharevba (1968), p. 26
  5. West African Journal of Archaeology, Editorial Board WAJA, p.144