Ipetumodu

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Àwòrán kájúkáko Ipetumodu

Ilu Ipetumodu je ilu nla kan ni ile yoruba ni apa iwo-orun guusu ile Naijiria, osi je ilu pataki kan ni Ipinle Osun ti osi je oluulu Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Àríwá Ife. ilu yi ni ile iwe fasiti aladani kan ti oruko re nje oduduwa university ati ile iwe girama ti oje ti ijoba maarun ati ile-iwe federal government girls' college. ise ti awon ipetumodu ma n se ni ise agbe ati ise amokoko.

itan ilu ipetumodu[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A te ilu ipetumodu do lati owo awon akoni, orunmila ati obatala ti won kowoorin pelu oduduwa lati aringbungbun ila-orun aye,awon ni won jo jagun gba ile-ife ti won si le awon eya igbo jade kuro ni ile-ife. Akalako ti ise omo obatala ti iya re si je adetinuwe tii se omobinrin oduduwa ni apetumodu akoko.O ma n pa etu bo odu ifa re,ibe ni oruko "a pa etu bo odu" ti odi ipetumodu ti jade wa.