Isaac Kwallu

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ìwé-alàyé[ìdá]
Isaac Kwallu
Ọjọ́ìbí29 June 1974
Orílẹ̀-èdèỌmọ Nigeria
Iṣẹ́Òṣèlú
Political partyPeople's Democratic Party (PDP)

Isaac Kyale Kwallu (wọ́n bí i lọ́jọ́ 29 oṣù kẹfà ọdún 1974) jẹ́ oníṣòwò àti òṣèlú ọmọ Nigeria. Ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ aṣojú-ṣòfin ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin Nigeria ẹlẹ́ẹ̀kẹwàá tó ṣojú fún ẹkùn-ìdìbò Mikang/Qua’an-Pan/Shendam ti Ìpínlẹ̀ Plateau.[1]

Òṣèlú[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Kwallu jẹ́ alága ìjọba-ìbílẹ̀ Qua’an-pan ní Ìpínlẹ̀ Plateau lábẹ́ àsíyá ẹgbẹ́-òsèlú All Progressive Congress (APC). Àwọn aṣòfin ìjọba-ìbílẹ̀ Qua'an-Pan rọ̀ ọ́ lóyè lọ́jọ́ karùn-ún oṣù kẹjọ ọdún 2020[2] lẹ́yìn náà ni àwọn ọmọ ilé ìgbìmò aṣòfin Ìpínlẹ̀ Plateau náà dá a dúró ráńpẹ́.[3][4] Ilé-ẹjọ́ Gíga ti Ìpínlẹ̀ Plateau dáa padà sípò lọ́jọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹsàn-án ọdún 2021.[5][6]

Ní ìdìbò ọdún 2023, ó wọlé ìbò láti sójú ẹkùn-ìdìbò ìjọba àpapọ̀ Mikang/Qua’an-Pan/ Shendam láti ṣojú wọn nílé ìgbìmò aṣojú-ṣòfin lábẹ́ ẹgbẹ́ òsèlú People's Democratic Party (PDP).[7] Hon. John Dafaan ti ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress kò gbà èsì ìdìbò rẹ̀ wọlé, nítorí ìdí èyí ó gbé e lọ sí iwájú ìgbìmọ̀ kòtẹ́milọ́rùn tí ìdìbò.[8] ṣùgbọ́n ìgbìmọ̀ náà dá Kwallu láre pé òun gangan ló wọlé.[9] Ilé-ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ló wá padà da ìbò rẹ̀ nù pé kò wọlé, tí wọ́n sì pàṣẹ pé Hon. John Dafaan ló wọlé[10]

Ẹ wòyí náà[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. YAKUB, ABDULRASHEED (2023-03-07). "INEC releases full list of elected lawmakers for Nigeria's 10th Assembly". Peoples Gazette (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-07-02. 
  2. "Breaking : Quan Pan LGC Chairman Impeached". Daybreak, Politics, Entertainment, Sport (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-08-05. Retrieved 2023-07-12. 
  3. Shittu, Muhammad Tanko (2020-08-06). "In Plateau state, Quan'pan LG boss impeached, deputy sworn-in – Blueprint Newspapers" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-07-02. 
  4. astutesofts (2020-06-30). "PLHA suspends Qua’an Pan, Kanam LG chairmen" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-07-06. 
  5. Daniels, Ajiri (2021-09-17). "Jos High Court reinstates impeached Plateau Council Chairman". The Sun Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-07-02. 
  6. "High Court reinstates ‘impeached’ LG boss". Daily Trust (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-09-18. Retrieved 2023-07-02. 
  7. "Plateau State Senate And House Of Representative 2023 Election Winners". Media Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2023-02-27. Retrieved 2023-07-02. 
  8. "Hon John Dafaan ,APC, Files Petition To Challenge PDP Over Party Structures INEC , Isaac Kwallu" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2023-06-07. Retrieved 2023-07-02. 
  9. admin (2023-09-01). "Tribunal upheld election of Plateau Reps member, Isaac Kwallu for Qua'an-Pan, Shendam, Mikang Federal constituency". Century News Update (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-12-05. 
  10. Editor, Online (2023-10-27). "Appeal Court Overturns Representative Member's Election: John Dafaan (APC) Declared Winner". Daybreak, Politics, Entertainment, Sport (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-12-05.