Jo-anne Reyneke

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jo-anne Reyneke
Ọjọ́ìbíJo-anne Reyneke
Oṣù Kẹfà 2, 1988 (1988-06-02) (ọmọ ọdún 35)
Vereeniging, Gauteng, South Africa
Ẹ̀kọ́Russell High School (Pietermaritzburg)
Iṣẹ́Actress
Ìgbà iṣẹ́2008 - present
Alábàálòpọ̀Thami Mngqolo (2008-18)
Àwọn ọmọ2

Jo-Anne Reyneke (bíi ni ọjọ́ kejì oṣù kẹfà ọdún 1988) jẹ́ òṣèré ni orílẹ̀ èdè South Áfríkà tí ó gbajúmọ̀ fún ipá Pearl tí ó kó nínú eré Muvhando àti Prudence Oliphant nínú Rythm City.[1]

Ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bíi sì ìlú Vereeniging ni ilẹ̀ Guateng. [2]Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Russell High School, níbẹ̀ sì ni ó ti nifẹ sí eré ṣíṣe. Ó tesiwaju sì ilẹ̀ ẹ̀kọ́ Movietech Film and Television School ní Durban níbi tí ó tí kẹ́kọ̀ọ́ orin kíkọ àti eré ṣíṣe.[3]

Iṣẹ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ni ilẹ̀ iṣẹ́ The Playhouse Company, níbi tí ó tí kópa nínú eré The Game. Duma Ndlovu tí ó jé olùdarí ère Muvhango, fún Reyneke ni anfaani lati kópa nínú eré náà gẹ́gẹ́ bíi Pearl, èyí sì lo je ki Reyneke tí gbajúmọ̀.[4] Ní ọdún 2013, ó fi eré Muvhango sílẹ̀, ó sì kópa nínú eré Intersexions àti Rhythm City ni ọdún náà. Ní ọdún 2019, ó kópa nínú eré ẹ̀fẹ̀ tí àkọ́rí rẹ̀ jẹ́ Black Tax.[5]

Ìgbéyàwó rẹ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọdún 2008, Jo-Anne Reyneke ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú Thami Mngqolo. Wọn bíi ọmọ méjì tí orúkọ wọn jẹ́ Uvolwethu(bíi ní ọdún 2013) àti Lungelo(bíi ni ọdún 2015). Ní ọdún 2018, òhun àti ọkọ rẹ̀ pínyà.[6][7]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]