Kefee

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Kefee
Background information
Ọjọ́ìbí(1980-02-05)Oṣù Kejì 5, 1980
Sapele, Delta, Nigeria
AláìsíJune 12, 2014(2014-06-12) (ọmọ ọdún 34)
Los Angeles, California, United States
Irú orinGospel
Occupation(s)Singer
Years active2000–2014
Associated actsTimaya

Kefee Obareki Don Momoh (ọjọ́ karùn-ún, oṣù kejì 1980 – ọjọ́ Kejìlá, oṣù kẹfà 2014), tí wọ́n tún máa ń pè ní orúkọ ìtàgé rẹ̀ Kefee, jẹ́ olórin obìnrin àti a-kọ-orin Nàìjíríà.

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìgbésí-ayé[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí i ní Sápẹ́lẹ́ ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù kejì , 1980[1][2] sínú ìdílé Andrew Obareki tí wọ́n fi ìgbà kan jẹ́ Díkọ́ọ̀nì nínú ìjọ tí àwọn òbí ọkọ rẹ tẹ́lẹ̀ rí, Alec Godwin dá sílẹ̀. Kefee kẹ́kọ̀ọ́jáde ní Yunifásítì ti Benin pẹ̀lú ìwé ẹ̀rí nínú Business Administration. Nígbà tí ó ń dàgbà, ó máa ń kópa nínú àwọn ètò ìjọ pàápàá kíkọrin nínú ẹgbẹ́ akọrin ìjọ.[3]

Iṣẹ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Bí ìfẹ́ rẹ̀ sí orin kíkọ ṣe ń gbòòrò sì, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ orin sílẹ̀, ó sì ń ṣe àkọsílẹ̀ orin. Ní 2000, ó fi àwo-orin tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Trip" léde, èyí sì jẹ́ kí ó rọrùn fún un láti wọnú agbo àwọn olórin Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí i olórin ìhìnrere. Ní 2003, ó bọwọ́lùwé àdéhùn iṣẹ́ pẹ̀lú Alec's Entertainment, ilé-iṣẹ́ orin tí adarí ẹgbẹ́ akọrin rẹ̀ tẹ́lẹ̀ dá sílẹ̀, ó sì fi àwo-orin àkọ́kọ́ lábẹ́ ilé-iṣẹ́ yìí Branama léde láìpẹ́ lẹ́yìn àsìkò náà. Àwo-orin Branama jẹ́ kí ó di ìlú mọ̀-ọ́n-ká gẹ́gẹ́ bí i olórin ìhìnrere pẹ̀lú bí ó ṣe yá ní títà ní ilé àti lókè òkun. Branama ta ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án késẹ́ẹ́ẹ̀tì láàárín ọ̀sẹ̀ mẹ́ta àti ó lé ní mílíọ̀nù méjì CD/VCDs láàárín oṣù kan. [4] Ó dúró gẹ́gẹ́ bí i Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ tí ó yanjú gẹ́gẹ́ bí i olórin ìhìnrere Nàìjíríà. Àwọn orin tí àwọn ènìyàn mọ̀ jù nínú àwọn orin tí ó gbòdekàn tí olóògbé olórin yìí kọ ni "Branama" àti "Kokoroko"

Àwọn àmì-ẹ̀yẹ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n fún un ní àmì-ẹ̀yẹ International Young Ambassador for Peace Award ní 2009.[5] Kefee gba 2010 Headies Awards for Best Collaboration pẹ̀lú Timaya fún "Kokoroko".

Ìgbésí ayé[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Kefee ṣe ìgbéyàwó ní ẹ̀ẹ̀mejì. Ó fẹ́ Alec Godwin fún ọdún mẹ́ta títí di ọdún 2008. Ó fẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ orí rédíò Teddy Esosa Don-Momoh ní ọjọ́ kẹta, oṣù kẹta, ọdún 2013 ní Sápẹ́lẹ́, ìpínlẹ̀ Delta.[6]

Ikú àti bí wọ́n ṣe sin ín[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan sọ pé ohun tí ó fa ikú rẹ̀ ni pre eclampsia, Kefee Obareki Don Momoh kú ikú lung failure ní ilé ìwòsàn kan ní Los Angeles, California ní ọjọ́ Kejìlá, oṣù kẹfà, ọdún 2014.[7][8] Ó ti wà ní ipò coma fún ọjọ́ márùndínlógún

Wọ́n sin ín ní ọjọ́ ẹtì. Ọjọ́ kọkànlá, oṣù kejè 2014 ni ìlú rẹ̀ Okpara Inland, ìjọba ìbílẹ̀ Ethiope East ti Ìpínlẹ̀ Delta, Nàìjíríà .[9]

Discography

Àwọn Àwo-orin
  • Branama (2003)
  • Branama 2 (2005)
  • A Piece Of Me (2008)
  • A Chorus Leader (2012)
EPs
  • Dan Maliyo (2012)
Àwo-orin lẹ́yìn tí ó kú
  • Beautiful (2015)

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Kefee to be buried July 11". Premium Times. July 3, 2014. http://www.premiumtimesng.com/arts-entertainment/164358-kefee-to-be-buried-july-11.html. Retrieved September 8, 2015. 
  2. Ezeh, Maryjane (February 5, 2015). "Kefee Comes Alive Today At Her First Memorial Birthday Concert". NigeriaFilms.com. http://www.nigeriafilms.com/news/31413/46/kefee-comes-alive-today-at-her-first-memorial-birt.html. Retrieved September 8, 2015. 
  3. Erhariefe, Tony Ogaga; Chima, Nkechi (June 14, 2014). "How music star, Kefee died". The Sun. http://sunnewsonline.com/new/music-star-kefee-died/. Retrieved September 8, 2015. 
  4. "Kefee". afrobios.com. Archived from the original on October 21, 2022. Retrieved September 15, 2020. 
  5. "Kefee becomes UN Peace Ambassador". NigeriaFilms.com. February 17, 2009. Retrieved August 26, 2014. 
  6. Osagie Alonge (5 June 2014). "Kefee’s husband confirms singer is in coma". Nigerian Entertainment Today. Thenet.ng. Retrieved 15 June 2014. 
  7. "Gospel singer, Kefee is Dead". The Nigerian Voice. http://www.thenigerianvoice.com/news/149521/1/gospel-singer-kefee-is-dead.html. 
  8. "Nigerian gospel singer Kefee dies". BBC News – Africa. BBC. Archived from the original on 2014-07-14. Retrieved 2022-04-30. 
  9. "Adieu Kefee...Emotional Photos as Gospel Singer is Laid to Rest in Sapele". Bella Naija.