Ken Watanabe

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ken Watanabe
Watanabe ní ibi ìsí Memories of Tomorrow
Ọjọ́ìbíOṣù Kẹ̀wá 21, 1959 (1959-10-21) (ọmọ ọdún 64)
Hirokami, Niigata, Japan
Iṣẹ́Actor
Ìgbà iṣẹ́1979Àdàkọ:Endashpresent
Olólùfẹ́
  • Yumiko Watanabe
    (m. 1983; div. 2005)
  • Kaho Minami
    (m. 2005; div. 2018)
Àwọn ọmọ

Ken Watanabe (渡辺 謙, tí a bí ní ọjọ́ kanlélógún oṣù Kẹ̀wá ọdún 1959) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè Japan. Ó gbajúmọ̀ láàrin àwọn elédè Gẹ̀ẹ́sì fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí General Tadamichi Kuribayashi nínú eré Letters from Iwo Jima àti gẹ́gẹ́ bi Lord Katsumoto Moritsugu nínú eré The Last Samurai, èyí tí ó mú kí wọ́n yán kún àwọn tí ó tó sí Academy Award for Best Supporting Actor. Àwọn àmì ẹyẹ míràn tí ó ti gbà ni Japan Academy Film Prize for Best Actor lẹ́mejì, àkọ́kọ́ ní ọdún 2007 fún Memories of Tomorrow àti èkejì ní ọdún 2010 fún Shizumanu Taiyō. Ọ̀pọ̀ tún mọ́ fún ipa rẹ̀ nínú eré Christopher Nolan pẹ̀lú àkọ́lé Batman Begins àti Inception, pẹ̀lú pẹ̀lú Memoirs of a Geisha, àti Pokémon Detective Pikachu.

Ní ọdún 2014, ó ṣeré nínú eré Godzilla gẹ́gẹ́ bi Dókítà Ishiro Serizawa àti nínú Godzilla: King of the Monsters. Ní ọdún 2022, ó ṣeré nínú eré HBO Max tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Tokyo Vice.