Khalil Halilu

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Khalil Halilu

EVC/CEO
Chief Executive Officer of the National Agency for Science and Engineering Infrastructure
Lọ́wọ́lọ́wọ́
Ó gun orí àga
1 September 2023
ÀàrẹBola Tinubu
AsíwájúBashir Gwandu
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí
Khalil Suleiman Halilu

29 Oṣù Kẹ̀wá 1990 (1990-10-29) (ọmọ ọdún 33)
Kano
Ẹgbẹ́ olóṣèlúAPC
ResidenceAbuja
Websitehttps://khalilhalilu.com

Khalil Halilu (tí a bí ní ọjọ́ 29 Oṣù Kẹwàá Ọdún 1990) jẹ́ ọmọ ilé-iṣẹ́ ìṣòwò àti alámọ̀já ìmọ̀-ẹ̀rọ̀ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, òntàjà àti igbákejì aláṣẹ lọ́wọ́lọ́wọ́ àti olùdarí àgbà ti National Agency for Science and Engineering Infrastructure (NASENI). Ààrẹ Bola Tinubu yàn án sí ipò yìí ní ọjọ́ kìíní oṣù kẹsàn-án ọdún 2023.

Igbesi aye ibẹrẹ ati ẹkọ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìlú Kano ní ìpínlẹ̀ Kano ni wọ́n bí Halilu. Ó lọ sí ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Rainbow ní Kano láti ọdún 1996 sí ọdún 2001. Ó parí ẹ̀kọ́ girama ní St Thomas Catholic School ní ọdún 2003 àti Prime College ní Kano ní ọdún 2006. Lẹ́hìn náà ni Halilu forúkọ sílẹ̀ ní University of Hertfordshire ní United Kingdom, níbi tí ó ti gba oyè ní Ìṣàkóso Ìṣòwò ní ọdún 2009, oyè Ìṣòwò Káríayé sì tẹ̀lẹ ní ọdún 2010.

Lẹ́hìn tí ó parí ẹ̀kọ́ láti ilé-ẹkọ gíga, Halilu ṣíṣe akọ̀wé ìṣàkóso ní Archimode & Associates. Lẹ́yìn náà ló parí iṣẹ́ National Youth Service Corps rẹ̀ ní Abuja.