Lẹ́tà gbẹ̀fẹ̀

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lẹ́tà Gbẹ̀fẹ́

Lẹ́tà gbẹ̀fẹ̀ ni irúfẹ́ lẹ́tà tí a ma ń ká sí àwọn ará, ẹbí, ọ̀rẹ́ àti iyèkan ẹni. Ìdí tí wọ́n fi pe lẹ́tà yí ní gbẹ̀fẹ̀ ni wípé àyè gbà wá gidi-gidi láti dá àpárá, ṣẹ̀fẹ̀, ṣòfófó àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ nítorí ẹni tí a ń ke lẹ́tà náà sí jẹ́ a mọ̀ tẹ́lẹ̀ tí a sì ma ń bá ṣàwàdà.[1]

Àwọn ohun tí ó ṣe kókó nínú lẹ́tà yí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ohun anọ́kọ́ tí ó ṣe pàtàkì nínú lẹ́tà èyíkéyí tí a bá fẹ́ kọ ni

  1. Adaríẹ́sì : Èyí ni a lè pe ní atọ́ka olùkọ lẹ́tà, nítorí wípé adaríẹ́sì yí ni yóò sọ ní pàtó fún ẹni tí ó fẹ́ gba lẹ́tà ibi tí lẹ́tà náà ti ń bọ̀. Àdírẹ́sì kan ṣoṣo ni ó ma ń wà nínú lẹ́tà gbẹ̀fẹ̀, tí àdírẹ́sì náà yóò sì jẹ́ ti olùkọ lẹ́là ní a pa ọ́tún ojú-ewé ìwé wa. Ònkọ lẹ́tà lè ká àdírẹ́sì rẹ̀ ní ìlànà méjì; àkọ́kọ́ ni Ìlànà Olóòró àti Ìlànà Oníbú. Àpẹẹrẹ:


Ìlànà Olóòró

            Ojúlé Kẹwàá,
            Òpópónà Kalẹ̀jayé,
            Òṣogbo,
            Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.
            22 May,2017.

Ìlànà Oníbú

            Òpópónà Kalẹ̀jayé,
             Òṣogbo,
              Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.
               22 May,2017.

Amọ́ ṣá, ìlànà Olóòró ni àwọn ènìyàn fẹ́ràn jùlọ. Lẹ́yìn àdírẹ́sì ni ó kan Ìkíni. Àpẹẹrẹ: "Ìyá mi ọ̀wọ́n, Àbúrò mi àtàtà, Ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n" àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.[2] Lẹ́yìn Ìkíni ni ó kan Ìfáàrà. Èyí lè gba ọ̀nà oríṣiríṣi wá bí ònkọ lẹ́tà bá ṣe fẹ́. Yálà ó fẹ́ pilẹ̀ lẹ́tà kíkọ ni tàbí ó fẹ́ fèsì sí lẹ́tà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ kọ si bóyá látòkèrè ni tàbí nítòsí. Àpẹẹrẹ Ìfáàrà:

"Bàbá mi ọ̀wọ́n, inú mi dun láti kọ iwé yí sí yín, mo sì mọ́ wípé ayọ̀ àti àláfíà ni yóò ba yin gẹ́gẹ́ bí èmi náà ṣe wà? Ṣe dáadáa ni gbogbo ilé wà, àwọn àbúrò mi ń kọ́; ṣálàfíà ni wọ́n wà? Èyí ni bí ònkọ lẹ́tà gbẹ̀fẹ́ bá fẹ́ pilẹ̀ lẹ́tà kíkọ.[3]

Bí ònkọ lẹ́tà bá fẹ́ fèsì sí lẹ́tà tí ó ti rí gbà, yóò gbe kalẹ̀ bayi:

"Ìyá mi àtàtà, ṣe àlááfiá ni? Inú mi dun láti fèsì sí lẹ́tà tí ẹ ke sí mi ní ọjọ́ Kejì oṣù Kẹri, ọdún 2017 lórí owó ilé-ẹ̀kọ́ mi tí ẹ fi ránṣẹ́ sí mi"

Lẹ́yin èyí,ònkà lẹ́tà yóò sè gbogbo ohun tí ó bá fẹ́ sọ, tàbí ṣàlàyé sínú lẹ́tà rẹ̀ láàrín ola mẹ́ta sí mẹ́rin. Láti Ìfáàrà sí ibi tí ó pin sí ni àárín lẹ́tà

Lẹ́yìn èyí ni olùkọ lẹ́tà yóò ṣe ìkádí lẹ́tà rẹ̀ pẹ̀lú "Emi ni ọmọ yin tòótọ́ tàbí Temi ni ti yin ní tótóọ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àsùnmọ́.

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Informal letter sample - Letter writing". Speak English. 2013-08-20. Retrieved 2020-02-07. 
  2. "How to Write an Informal Letter in UK English + Example". St George International. 2017-07-27. Retrieved 2020-02-07. 
  3. "How to Write Informal Letters in English (With Examples)". Owlcation. Retrieved 2020-02-07.