Liptako

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Liptako jẹ́ àgbègbè kan ní ìwọ̀ oòrùn Áfríkà ní ayé àtijó. Àgbègbè Liptako nígbà náà jé ara ìlà oòrùn Burkina Faso, Gúúsù ìwọ̀ oòrùn Niger àti díẹ̀ nínú ilẹ̀ Mali. Àgbègbè náà jẹ́ ilẹ̀ òkè tí ó bẹ̀rẹ̀ láti apá ọ̀tún Odò Ọya, Liptako bá Liptako Emirate pín orúkọ, ilẹ̀ àwọn Mùsùlùmí Fulani kan tí Brahima Saidu dá kalẹ̀.[1][2] Orúkọ míràn tí wọ́n tún ń pe àgbègbè náà ni Liptako-Gourma, nítorí àwọn ènìyàn Gourmantche people tí ó ń gbé ibẹ̀.

Liptako ní ayé òde òní, tí ọ̀pọ̀lopọ̀ ilẹ̀ rẹ̀ wà lábẹ́ Burkina Faso, pẹ̀lú agbègbè Tera àti Say, àti apá ibi kan ní Mali, jẹ́ ilẹ̀ òkè pẹ̀lú olùgbé tí ó kéré níye. Àwọn olùgbé ibè tí ó jẹ́ ẹ̀yà Fula, tí a tún mọ̀ sí "Liptaako" tàbí Liptako Fula, jẹ́ olùsọ́ àgùntàn àti màlúù.[3] Say, àgbègbè itajà kan ní ẹgbẹ́ odò oya(Niger), tí ó gbajúmọ̀ ní àwọn ọdún 1800s, ní àwọn arajà tí ó ń gba ọ̀nà ọjà àwọn ẹ̀yà Fula nínú Liptako wá. Ní àwọn ọdún 1900s, wọ́n rí wúrà àti àwọn àlùmọ́nì míràn níbẹ̀,[4] èyí ni ó mú kí Liptako-Gourma Authority kalẹ̀ ní ọdún 1970.

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. J. F. Ade Ajayi, Unesco. International Scientific Committee for the Drafting of a General History of Africa (eds). Africa in the nineteenth century until the 1880s. UNESCO, University of California Press, (1998) ISBN 0-520-06701-0 pp. 269-71, 275, 276
  2. The Liptako Fula. Jamtan, Fulfulde encyclopedia. Accessed 2009-05-20.
  3. Fulani, Gurmanche of Burkina Faso Archived 2008-03-31 at the Wayback Machine.. Joshua Project, accessed 2009-05-20
  4. Gold and Base Metal Exploration on the Tialkam Exploration Licence, Liptako Region, Niger, West Africa. Summary of: 'Tialkam Permit, Liptako/Niger - Final Report'.- 20 pp, 14 maps and 19 annexes. GeoServices Int/Barrick/ Anglo-American. Accessed 2009-05-20