Mamman Nasir

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Nasir Mamman GCON (ọjọ kejì, oṣù July, ọdún 1929- ọjọ́ kẹtàlá, tí oṣù April, ọdún 2019) ni a fún lórúkọ Galadiman ti Katsina láti ọdún 1992 tí tí de ọdún 2019 jẹ oludajọ ilẹ̀ Nàìjíríà tó sìn ilé ẹjọ́ tí arẹ kò tẹmi lọrun láti ọdún 1978 de 1992[1].

Ìgbésí Ayé Mamman Nasir[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Mamman ni wọn bí ní ọdún 1929 sì Katsina. Ó jáde ní Collegi Kaduna (Èyí tó ti di Collegi Barewa) ni ọdún 1947 lẹ́yìn náà lo kàwé lórí imọ Látìn ni ile iwe gíga Collegi ti Ibadan. Ní ọdún 1956, Mamman kẹ́kọ̀ọ́ jáde lórí imọ òfin ni Ile Lincoln tó sì jẹ ọkan lára àwọn ará apá àríwá Naijiria tó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè lórí òfin láti gba ti Sokoto Caliphate tó ṣubú[2][3].

Arákùnrin náà di adajọ tí ilé ẹjọ́ gíga tí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni ọdún 1975. Ní ọmọ ọdún ọ̀kan dín ní àádọ́ta, ó fẹyinti tó sì di arẹ ilé ẹjọ́ kò tẹmi lọrun títí tá fi sọ di Galadima tí Katsina àti olórí àgbègbè Malumfashi[4][5].

Mamman kú sí ipinlẹ Katsina ni ọjọ kẹtàlá, oṣu April, ọdún 2019 lẹyin àìsàn rán pẹ[6][7].

Àwọn Itọkasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "NASIR, Alhaji Maman". Biographical Legacy and Research Foundation. 2016-11-03. Retrieved 2023-10-05. 
  2. "JUSTICE MAMMAN NASIR". Nigerian Voice. 2011-11-13. Retrieved 2023-10-05. 
  3. "The Sokoto Caliphate and its Legacies (1804-2004)". dawodu.com. Retrieved 2023-10-05. 
  4. "Mamman Nasir: From the Bench to the throne". Archived from the original on 29 April 2015. Retrieved 29 April 2015. 
  5. "Adagbo Onoja: Justice Mamman Nasir, the North and 2015". Daily Post Nigeria. 2013-04-23. Retrieved 2023-10-05. 
  6. "BREAKING: Former Court of Appeal President, Nasir is dead". Daily Trust. 2019-04-13. Retrieved 2023-10-05. 
  7. "Allah ya yi wa Justice Mamman Nasir rasuwa - BBC News Hausa". BBC News Hausa (in Èdè Hausa). 2019-04-13. Retrieved 2023-10-05.