Mathew Hassan Kuka

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Mathew Hassan Kuka (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kọkànlélọ̀gbọ̀n oṣù kẹjọ ọdún 1952) jẹ́ Bíṣọ́ọ̀bù àgbà tí olu-ìjọ Kátólìkì tí ìpínlẹ̀ ṣókótó

Ìgbà èwe àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Bíṣọ́ọ̀bù Kukah lọ́jọ́ kọkànlélọ̀gbọ̀n oṣù kẹjọ ọdún 1952 ní ìlú Anchuna, tí Ikulu ní ìjọba-ìbílẹ̀ Zangon Kataf ní ìpínlẹ̀ Kaduna lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[1] Kukah bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé àkóbẹ̀rẹ̀ ní St. Fidelis Primary School, Zagom, ó tẹ̀ síwájú ní ilé ìwé kékeré ìkẹ́kọ̀ọ́ àwọn àlùfáà ìjọ Kátólìkì ti St. Joseph Minor Seminary, ní ìlú Zaria. Ó kàwé sí I ní St. Augustine Major Seminary Jos, ní ìpínlẹ̀ Plateau, níbi tí ó ti kàwé gboyè ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú ìwòye nǹkan àti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kukah gboyè àlùfáà ìjọ Kátólìkì lọ́dún 1976. Ó kàwé gboyè dípólómà nínú ìmọ̀ ẹ̀sìn ní University of Ibadan, bákan náà ní Pontifical Urban University ní ìlú Róòmù lọ́dún 1976. Ó kàwé gboyè dìgírì kejì nínú ìmọ̀ ìpẹ̀tùsáwọ̀ ní University of Bradford, lórílẹ̀ èdè United Kingdom lọ́dún 1980. Kukah kàwé gboyè Ọ̀mọ̀wé (PhD) ní School of Oriental and African Studies (SOAS) ti University of London lọ́dún 1990.[1] At some unspecified point, he studied at the University of Oxford, in Oxford, in Oxfordshire, England, United Kingdom, and also at Harvard University, in Cambridge, Massachusetts, in Greater Boston, in the United States.[2]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]