National Youth Service Corps

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
National Youth Service Corps
Fáìlì:National Youth Service Corps logo.jpg
Formation22 May 1973
HeadquartersAbuja, Nigeria
Websitehttp://www.nysc.gov.ng/
A Corps member and his students
Tap water project done by Corps members
Corp members at their community development service

Àjọ eletò Agùnbánirọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà tí a mọ̀ sí  (NYSC)  The National Youth Service Corps jẹ́ ètò tí ìjọba ilẹ̀ Nàìjíríà gbé kàlẹ̀ fún àwọn ọ̀dọ́ langba tí wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ jáde ilé ẹ̀kọ́ ńlá ńlá jáàkiri ilẹ̀  Nàìjíríà, léte àti lè jẹ́ kí àwọn ọ̀dọ́ wọ̀yí ó lè mú iṣẹ́ ìdàgbà sókè ilẹ̀ baba wọn ní ọ̀kúnkún dùn. Bì ó tilẹ̀ jẹ́ wípé àwọn ológun ilẹ̀  Nàìjíríà, kìíbfipá múni láti dara pọ̀ mọ́ iṣẹ́ kgun. Àmọ́, ní ọdún 1973 ìjọba ilẹ̀ Nàìjíríà fòté lé wípé kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gboyè ilé ẹ̀kọ́ Fásitì àti Pólì ilẹ̀ Nàìjíríà ó ma kópa nínú iṣẹ̀ agùnbánirọ̀ ní ikẹ̀ Nàìjíríà fún ọdún kan péré.[1] Èyí bi a mọ̀ sí ọdún ìsinlẹ̀ baba ẹni. Ọ̀gbẹ́ni Ahmadu Ali ló kọ́kọ́ jẹ́ adarí àgbà àkọ́kọ́ fún àjọ náà títí di ọdún 1975.[2]  Tí èni tó eà níbẹ̀ lásìkò yí jẹ́ Director-General ìyẹn ọ̀gágun Brig. Gen. Sule Zakari Kazaure.[3]

Bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n dá NYSC kalẹ̀ ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù Karùún, ọdún 1973 gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà kan pàtàkì láti mú ìfọwọ́-sowọ́pọ̀, àtúnṣe àti àtúntò bá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lẹ́yìn ogun abẹ́lé tó kọjá. Ìdá àjọ yìí kalẹ̀ wà níbàámu pẹ̀lú ìlà òfin orí No. 24 tí ó sọ wípé " Pẹ̀lú ìwòye láti fẹsẹ̀ ìwúrí àti ìdàgbà-sókè tó lọ́ọ̀rìn múlẹ̀ pẹ̀lú ìbáṣepọ̀ tó pegedé láàrín àwọn ọ̀dọ́ langba tì wọ́n wá láti àwùjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún ìlọ síwájú ìṣọ̀kan orílẹ̀ èdè Nàìjíríà".[4]

Bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Gbogbo àwọn Agùnbánirọ̀  pátá ni wọ́n ma ń gbé kọ sí ibi tí wọn yóò ti ṣiṣẹ́ sin ilẹ̀ baba wọn yàtọ̀ sí ìlú tí wọ́n ti bí wọn kí wọ́n lè dà pọ̀ mọ́ àwọn akẹgbẹ́ tí ẹ̀yà wọn yàtọ̀ sí tiwọn ní ìlú rí wọ́n bá gbé wọn sí. Ìgbésẹ̀ yí ni ìjọba gbà lérò láti mú ìṣọ̀kan àti láti lè jẹ́ kí àwọn Agùnbánirọ̀ ó mọ àpọ́nlé  àṣà àwọn tẹ̀yà tó kù. Wọ́n ma ń ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti ìgbaradì fún gbogbo àwọn Agùnbánirọ̀ dún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta gbáko ní agbo tí àwọn ológun ń ṣàkóso rẹ̀, bí ó bá sì ti di òpin ọ̀sẹ̀ kẹ́ta wọn yóò ṣe ayèyẹ ìjáde fún wọn, lẹ́yìn ẹyí ni wọn yóò gbé wọn lọ sí ìjọba ìbílẹ̀ tí wọn yóò ti si ilẹ̀ baba wọn tí wọ́n ń pè ní (PPA). Níbí ni àwọn Agùnbánirọ̀ ti gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ sinlẹ̀ baba wọn gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ ìjọba tí wọn yóò sì ma pa ọjọ́ kan jẹ nínú ọjọ́ ọ̀sẹ̀ fún iṣẹ́ ìdàgbà-sókè agbègbè wọn, lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ṣe èyí fún ọdún kan gbáko ni ìjọba yóò tó yànda wọọn tí wọn yóò sì gbàwé ẹ̀rí lìfọkàn-sìn  láti ọwọ́ ìjọba àpapọ̀.

Àǹfàní ètò náà[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

.Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ jáde ilé ẹ̀kọ́ gíga kò ní àǹfàní kan kan láti wáṣẹ́ tàbí ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìjọba tàví àdáni láì ṣe wílé wọ́n parí ìsinlẹ̀ baba won fún ódún kan gbáko yìí, tàbí kí ẹni tí ó bá ti kọjá ọmọ ọgbọ̀n ọdún tàbí tí kò oé lára nínú wọn ó gba lẹ́tà àdáyanrí. Bákan náà sì ni àwọn Agùn-bánirọ̀ ní àǹfàní láti kọ́ nípa àṣà ibòmíràn tí wọ́n bá gbé wọn lọ.

Àwọn Èròngbà Àjọ Agùnbánirọ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n ṣe àkóónú àwọn èròngbà àjọ Agùnbánirọ lọ́kan-o-jọọ̀kan sábẹ̀ iwé ofin orí Kọkànléláàdọ́ta (Decree No. 51) ti ọjọ́ Kẹrìnlá oṣù Karùún ọdun 1993 báyìí:

  • Láti jẹ́ kí àwọn ọ̀dọ́ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ó lè ní ẹ̀kọ̀ nípa ìfọkàn-sìn níbi iṣẹ́ tí wọ́n gbé lé wọn lọ́wọ́, àti ẹ̀mí ìfarajìn àti ìlóòtọ́ níbi kíbi tí wọọ́n bá ti bá ara wọn. 
  •  Láti lè kọ́ wọn nípa ìjẹ́ olùbọ̀wọ̀ àṣà, nípa fífún wọn ní àǹfàní láti lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀yà tókù tó yàtọ sí tiwọn. 
  •  Láti lè jẹ́ kí dàgbà nípa ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn tí wọ́n ti kọ́ ní agbo tí wọ́n wà nígbà tí wọ́n dàpọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀yà mìíràn níbi ẹ̀kọ́ wọn, tí yóò sì ṣègbélárugẹ fún ìṣọ̀kan orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. 
  •  Láti lè jẹ́ kí àwọn ọ́dọ́ ó lè ní ẹ̀mí ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ara wọn nípa kíjọ́ àkọ̀tun iṣẹ́ tí yóò kè jẹ́ kí wọ́n lè dá dúró fúnra wọn.
  •  Láti lè jẹ́ kí wọ́n kópa nínú ìdàgbà-sójè ètò ọrọ̀ ajé orílẹ̀-èdè  Nàìjíríà. Láti lè pa ìwà ìkórira àti àìmọ̀kan kí ìṣọ̀kan le wà láàrín àwọn ẹ̀yà ilẹ̀ Nàìjíríà. 
  •  Kí ìrẹ́pọ̀ àti ìfọwọ́-sowọ́pọ̀ tí yóò mú ìgbélárugẹ bá orílẹ̀-èdè lè jọba Nàìjíríà.
  •  Kí àwọn ọ̀dọ́ Agùnbánirọ̀ ó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn òṣìṣẹ ìpínlẹ̀ míràn tó yàtọ̀ sí tiwọn. Kí iṣẹ́ àjọṣepọ̀ àwọn ọ̀dọ́ agùnbánirọ̀ ó lè ran ìdàgbà-sókè orílẹ̀-èdè lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá nílò wọn. 
  •  Kí àwọn ọ̀dọ́ Agùnbánirọ̀ ó lè gbé pọ̀ pẹ̀lú àeọn ẹ̀yà míràn ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Láti lè jẹ́ kí àwọn ọdọ́ ilẹ̀ Nàìjíríà ó lè ní ìfaradà àti ìgbà-mọọ́ra àwọn akẹgbẹ́ wọọn tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́sìn míràn. 
  •  Kí ìwúrí lè wà fún àwọn ọ̀dọ́ Agùnbánirọ̀ láti lè wáṣẹ, ṣiṣẹ́ níbi kíbi ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lẹ́yìn ọdún kan tí wọ́n ti sinlẹ̀ baba wọn, tí yóò sì ṣe ìgbélárugẹ fún ìgbòkè-gvodò àwọn òṣìṣẹ́ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà  
  •  Kí àwọn agbani síṣẹ́ tí wọ́n gba àwọn ọ̀dọ́ Agùnbánirọ̀ mọ́ra ó lè yẹ̀ àwọ́n Agùnbánirọ̀ náà wò fún ọdún kan kí wọ́n sì lè gbà wọ́n síṣẹ́, láì wo ìlú tàbí ẹ̀yà tí wọ́n ti wá.

Criticisms[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìgbésẹ̀ àjọ Agùnbábirọ̀ yí ti bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìfẹnu ṣátá pàdé láti ọ̀dọ̀àwọn ọ̀dọ́ Agùnbánirọ̀ náà nípa ọowó ọ̀yà tí kò tó ǹkan tí ìjọba ń san fún àwọn ọ̀dọ́ Agùnbánirọ̀ náà.[5] Ọ́pọ̀ àwọn ọ́fọ́ Agùnbánirọ̀ ló sì yi ké gbàjarè nípa bí àjọ náà ṣe rán wọn lọ síbi tí ẹ̀mí wọn kò ṣe dè látàrí ìjà ẹ̀sìn, ẹ̀yà àti tòṣèlú ṣe ń ṣekú pa wọn láìrò tẹ́lẹ̀.[6] Ọ̀pọ̀ nínú àwọn alẹ́nu-lọ́rọ̀ láeùjọ ló yi pè fún ìwagbọò dẹ́kun sí iṣẹ́ àjọ náà látàrí ètò àbò tó mẹ́hẹ ní orílẹ̀ -èdè Nàìjíríà., tí ọ̀pọ̀ sì sọ wípé àjọ náà ti kùnà níbi èrò tí wòn fi gbe kalẹ̀, tí wọ́n sì ri gẹ́gẹ́ bí ọ̀bà ìfàkókò, ìfọ̀mọ nìyàn àti ohun àlùmọ́nì ìlú ṣòfò lásán  àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àdàkọ:WhoÀdàkọ:Who

Àwọn ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Marenin, Otwin (1990). "Implementing Deployment Policies in the National Youth Service Corps of Nigeria". Comparative Political Studies (London: SAGE Publishers) 22 (4): 397–436. doi:10.1177/0010414090022004002. http://cps.sagepub.com/cgi/content/abstract/22/4/397. Retrieved 25 February 2009. 
  2. "A Cup of Tea From Yakubu Gowon". AllAfrica. 22 October 2012. http://allafrica.com/stories/201210220609.html. Retrieved 28 December 2015. 
  3. "About DG". NYSC.gov.ng. Archived from the original on August 31, 2015. Retrieved September 8, 2015. 
  4. "NYSC - About Scheme". www.nysc.gov.ng. Retrieved 2018-06-06. 
  5. "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2013-09-27. Retrieved 2018-12-27. 
  6. Visit The Official NYSC Interactive Website/ Forum http://www.nyscforum.org

Àwọn ìjá-sóde[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]