Obafemi Lasode

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ọbáfẹ́mi Lásọdé
Ọjọ́ìbí4 Oṣù Kejìlá 1955 (1955-12-04) (ọmọ ọdún 68)
Port Harcourt, Rivers State, Nigeria.
Orílẹ̀-èdèỌmọ Nigeria
Ọmọ orílẹ̀-èdèỌmọ Nigeria
Iṣẹ́olórin
oǹkọ̀wé orin
playwright
olóòtú sinimá
olùdarí sinimá
Ìgbà iṣẹ́1983– àsìkò yii

Ọbáfẹ́mi Lásọdé Yo-Obafemi Lasode.ogg Listen(tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹrin oṣù Kejìlá ọdún 4 1955) jẹ́ gbajúmọ̀ olórin, olùdarí àti olóòtú sinimá , ó jẹ́ oǹkọ̀wé àti olóòtú orin, eré-oníṣe ọmọ Nigeria.[1] Òun ni olùdarí-àgbà ilé-iṣẹ́ Even-Ezra Nigeria Limited, tí ó ṣe agbátẹrù sinimá olókìkí nì, Sango tí ó gba ọ̀pọ̀ àmì-ẹ̀yẹ lọ́dún 1997.[2][3]

Ìgbésí-ayé rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Ọbáfẹ́mi Bándélé Lásọdé lọ́jọ́ kẹrin oṣù Kejìlá ọdún 1955 ní ìlú Port Harcourt, olú-ìlú Ìpínlẹ̀ Rivers lórílẹ̀-èdè Nigeria, ṣùgbọ́n tí àwọn òbí rẹ̀ jẹ́ ọmọ bíbí Abẹ́òkúta, ní Ìpínlẹ̀ Ògùn.[4]

Ó kàwé ní St. Gregory's College ní ìlú Ọbaléndé ní Ìpínlẹ̀ Èkó, níbi tí ó ti kàwé gbàwé ẹ̀rí West African Senior School Certificate.[5] Ó tesiwaju nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ tí ó sì kàwé gbàwé ẹ̀rí Bachelor of Science nínú ìmọ̀ Business administration ní ilé ẹ̀kọ́ Kogod School of Business, ní ìlú Washington, D.C.[6] Lẹ́yìn èyí, ó tún kàwé gbàwé ẹ̀rí Master of Science nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ìbánisọ̀rọ̀, Communication art láti Brooklyn College, City University of New York.[7]

Iṣẹ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó dára pọ̀ mọ́ ilé-iṣẹ́ Inner City Broadcasting Corporation, ti ìlú New York City lọ́dún 1983 gẹ́gẹ́ bí olùdarí ìpolongo, níbi tí ó ti gba Sonny Okosuns lálejò lọ́dún 1984 ní gbajúmọ̀ gbọ̀ngán àgbáyé nì, Apollo TheaterHarlem.[8]

Ó ṣe agbátẹrù ètò orin ilẹ̀ adúláwọ̀ Áfíríkà tí a mọ̀ sí Afrika in Vogue lórí pẹpẹ Radio Nigeria 2, ètò yìí bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1989, tí wọ́n sì ṣe é fún odidi ọdún kan gbáko.[9] In 1995, he established Afrika 'n Vogue/Even-Ezra Studios.[9]

Lọ́dún 1997, ó ṣe agbátẹrù àti olùdarí sinimá kan gbòógì tí ó gbàmì ẹ̀yẹ káàkiri ilẹ̀ adúláwọ̀ Áfíríkà tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́ Sango, gbajúmọ̀ sinimá tí wọ́n yàn láti ṣíde àjọ̀dún Minneapolis–Saint Paul International Film Festival lọ́dún 2002.[10] Òun ni oǹkọ̀wé àwọn ìwé wọ̀nyí tí àkọlé wọn ń jẹ́ Television Broadcasting: The Nigerian Experience (1959–1992),[11] tí wọ́n ń lò báyìí ní àwọn ilé-ìwé ifáfitì káàkiri Nigeria.[12]

Àwọn sinimá tí ó ti kópa[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Sango (1997)
  • Mask of Mulumba (1998)
  • Lishabi
  • Tears of Slavery

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Femi Lasode set to raise the bar with Stolen Treasures". The Sun News. 9 March 2014. Archived from the original on 18 January 2015. Retrieved 17 January 2015.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. "Lasode Returns to Nollywood, Builds Nigeria's First Film Village with N25million.". Starconnect Media. 26 January 2014. Archived from the original on 18 January 2015. Retrieved 18 January 2015. 
  3. Ṣàngó in Africa and the African Diaspora. Bloomington and Indianapolis: Indiana University Press. 2009. p. 141. ISBN 978-0253220943. https://books.google.com/books?id=7tILKOSn0qYC&q=Albert+Aka-eze&pg=PA141. Retrieved 18 January 2015. 
  4. Jonathan Haynes, ed (2000). Nigerian Video Films. Ohio University Center for International Studies. ISBN 9780896802117. https://books.google.com/books?id=OOgm9GtCzW4C&q=Sango,+the+legendary+african+King+movie+Distributor&pg=PA1. Retrieved 18 January 2015. 
  5. "Femi Lasode speaks on SANGO The legendary Afrikan King at 10". The Nigerian Voice. 5 July 2008. Retrieved 18 January 2015. 
  6. Afro-optimism: Perspectives on Africa's Advances. Praeger. 2003. p. 37. ISBN 9780275975869. https://books.google.com/books?id=-2wyFaU_FVkC&q=Television+broadcasting:+The+Nigerian+Experience+(1959+-+1992).&pg=PA37. Retrieved 18 January 2015. 
  7. "Only advancement of technology can curb piracy -FEMI LASODE". nigeriatell.com. Archived from the original on 18 January 2015. Retrieved 18 January 2015. 
  8. "About the director — Obafemi Bandele Lasode". African Film Festival New York. Retrieved 18 January 2015. 
  9. 9.0 9.1 "Obafemi Lasode", International Contest 2000 – Artist's Page, A Song For Peace in the World.
  10. "Femi Lasode: Life after Sango". The Punch – Nigeria's Most Widely Read Newspaper. Archived from the original on 18 January 2015. Retrieved 18 January 2015.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  11. Obafemi Lasode, Television Broadcasting: The Nigerian Experience (1959–1992), Caltop Publications (Nig.), 1993, ISBN 978-9783165335, at Amazon.
  12. Viewing African Cinema in the Twenty-First Century. Ohio University Press. 2010. p. 24. https://archive.org/details/viewingafricanci0000unse. Retrieved 18 January 2015. "Television broadcasting: The Nigerian Experience (1959–1992)."