Olusegun Agagu

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Olusegun Agagu
Gómìnà Ipínlẹ̀ Òndó 15un
In office
May 29, 2003 – February 23, 2009[1]
Arọ́pòOlusegun Mimiko
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbíOṣù Kejì 16, 1948 (1948-02-16) (ọmọ ọdún 76)
Okiti-Pupa, Ipinle Ondo, Nigeria
Ẹgbẹ́ olóṣèlúPeople's Democratic Party
(Àwọn) olólùfẹ́Olufunke Agagu.

Olusegun Kokumo Agagu (born 16 February 1948) je oloselu omo ile Naijiria ati Gomina Ipinle Ondo lati 29 May, 2003 titi di 23 February, 2009 nigbati Ile-ejo Alatunejoda ni Ilu Benin fagile idiboyan April 2007 nitori pe ko bo fin mu.

Wọ́n bí i ní ferbruary 16, 1948 ní Òkìtìpupa; Ondo State. Ó bẹ̀rẹ̀ ilé-ẹ̀kọ́ ní St Luké’s Anglican School, Òkìtì pupa ní 1954. Ó tún lọ sí Ebenezer Methodist School, Òkè-Àdó, Ìbàdàn ní 1958. Ó tún lọ sí Baptist Primacy School, Sabon-gari, Kano. Ó wá parí ẹ̀kọ́ primary School rẹ̀ ní Ebenezer African Church School, Ibadan. Lẹ́yìn èyí, ó lọ sí ìbàdàn Grammar School ní 1961. Lẹ́yìn èyí, ó lọ sí University Ìbàdàn láti ka Botany. Torí pé ó mọ Geology dáadáa, wọ́n fún un ní ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ Gulf oil láti ka Geology lẹ́yìn ọdún kìíní. Lẹ́yìn ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní University, ó bá Guif oil ṣiṣẹ́ fún ọdún méjì kí ó tó wá gbṣẹ́ sí University of Ìbàdàn gẹ́gẹ́ bí Assistant Lecturer ní 1972. ó lọ kàwé fún oye master rẹ̀ ní University of Texas láàrin 1973 sí 1974. Ó gbá PhD ní Petroleum Geology ní ní University of Ìbàdàn ní 1978. Ní 1988. ó fi UI sílẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ síi ṣe òṣèlu. Kò pé lẹ́yìn èyí, ó di igbákejì Gómínà ìpínlẹ̀ Oǹdó. O sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe gómìnà ìpínlẹ̀ Oǹdó láti 2003 títí di ìgbà tí a ń kòwé yòí ní 2008.




Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]