Osman Digna

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́


Osman Digna
Osman Digna in old age
Bornc. 1840
Suakin
Died1926
AllegianceMahdist State of Sudan
Years of service1883 — 1899
RankEmir
Battles/warstree list
  • Mahdist War
    • Battles of El Teb
    • Battle of Tamai
    • Battle of Kufit
    • Battle of Suakin
    • Battle of Atbara
    • Battle of Umm Diwaykarat
    • Battle of Kufit

Osman Digna (Èdè larubawa: عثمان دقنة) (c. 1840 – 1926) jẹ olutẹle ilana ti Muhammad Ahmad,ẹni ti oun pe ara rẹ ni Mahdi ni sudan jẹ oludari ologun nigba ogun ti Mahdi. Gẹgẹbi ologun Mahdi to pegede julọ, Osman kopa pataki ninu igbesi aye Ọgagun Charles George Gordon ati ikuna sudan si idari ilẹ Turkey-Egypt.

Igbèsi Àye Osman[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Baba Osman Digna jẹ ẹya Kurd atipe iya rẹ wa lati ẹya Hadendoa lati ara Beja. A mọ arakunrin yi Osman Ali, oun gbe ni Alexandria, Egypt nibi to tin ṣe owo oko ẹru. Nigba ti ijọba fagile owo rẹ, arakunrin naa kopa ninu ija ti Ahmed 'Urabi'. Lẹyin ti ija Tel al-kebir (Ọjọ mẹ̀tala, óṣu September, ọdun 1882), arakunrin naa darapọ mọ ija ti Mahdi.

Osman gẹgẹbi Oludari ti Mahdi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Osman gba órukọ Digna ni to ri irugbọn rẹ tokun. Arakunrin naa dari awọn ogun to lagbara ni agbegbe Suakin. Ogun rẹ akọkọ jẹ eyi to jaguba ba ibudo kan ni ilẹ turkey ni Sinkat ni ọdun 1883. Nì ọjọ kẹrin, óṣu February, ọdun 1884, Osman jagun ba awọn ọmọ ogun ti ilẹ̀ Egypt ti Baker Pasha jẹ̀ oludari wọn. Eyi lo mu ki ijọba ilẹ British-Egypt ran ọmọ ogun rẹ lati doju ija kọ ni El Teb pẹlu oludari ọgagun Graham.

Osman Digna jẹ alẹjo oludari to ti doju ija kọ square Infantry ti ilẹ British, Osman gbajumọ larin ẹya British fun ijagbara rẹ. Nitori agbara oun ati awọn ọmọ ogun rẹ ni wọn yẹsi ninu iwe orin Kudyard Kipling "Fuzzy-Wuzzy". Osman ni a sọ ni órukọ ninu ijagun ti El-Teb, iwe órin ti William McGonagall. Kẹyin ti Khartoum jabọ si ọwọ awọn Mahdi lọwọ ati pe Ọgagun Gordon ku, wọn gbe ago ati ida Gordon le Osman lọwo lati fi ran awọn mahdi ni Suakin pe ógun ti ṣẹ.

Ni ọdun 1899, Osmon ja ijagbara fun awọn ologun ti mahdi eyi ti agbara rẹ ti dinku ni ọdun 1888 ni ilẹ Omdurman. Ni ogun Umm Diwaykarat, Osman farapa to si fi ori pamọ. Ni ọdun 1900, Ọwọ ba Osman ni agbegbe Rosetta nibẹ loti ṣẹwọn fun ọdun mẹjọ ni lẹyin naa lo gba itusilẹ tosi morile ilẹ Egypt tosiku ni ọdun 1926.

Itọkasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]