Remi Raji

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Aderemi Raji-Oyelade ti wọ̀n bi ní ọdún (1961)[1] jẹ́ akéwì ilẹ̀ Nàìjíríà tí ó ńkọ̀wé ni èdè gẹ̀ẹ́sì. Ó gbajúgbajà fún orúkọ ìsàmì rẹ̀, Remi Raji.[2]

Iṣẹ́ Ìríjú[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ara Salzburg àti ọ̀jọ̀gbọ́n tí ó n sàbẹ̀wò àti ǹkọ̀wé sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé ẹ̀kọ́ giga, lára wọn ni Southern Illinois Yunifásítì ti Edwardsville, Yunifásítì tí California ni Riverside àti Irvine, Yunifásítì tí Cape Town, South Africa, àti Cambridge Yunifásítì , UK, Raji ti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àròkọ tí a gbé jáde nínú àtẹ̀jáde bi Research in African Literatures àti African Literature Today. Ó ti ka àwọn ewì rẹ káàkiri ní ilẹ̀ Áfíríkà, aláwọ̀ funfun and Amẹ́ríkà. Ní ọdún 2005, ó jẹ́ óńkọ̀wé àlejò sí ìlú Stockholm, orílẹ̀ èdè Sweden.[3]

Àwọn ìwé ewì tí ó ti kọ ni wọ̀nyí Webs of Remembrance (ní ọdún 2001), Shuttlesongs America: A poetic guided tour (ní ọdún 2003), Lovesong for My Wasteland (ní ọdún 2005), Gather My Blood Rivers of Song (ní ọdún 2009) and Sea of My Mind (ní ọdún 2013). A ti sàyípadà àwọn ìwé Raji sí èdè Faransé, Jámánì , Kàtàlánù, Swedish, Ukrainian, Latvian, Croatian and Hungarian. Ó ti jẹ́ ọ̀mọ̀we ti Alexander von Humboldt si Yunifásítì ti Humboldt , ní ilẹ̀ Berlin, Jámínì.[3]

A dìbò fún Remi Raji gẹ́gẹ́ bi akọ̀wé alukoro fún Ẹgbẹ́ Àwọn Òǹkọ̀wé Nàìjíríà, ẹ̀ka Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ọdún 1989. Ipò kejì mìíràn tí à dìbò fun sí ni igbá-kejì alága ti Ẹgbẹ́ Àwọn Òǹkọ̀wé Nàìjíríà ní ọdún 1997. Ó di alága pàtàkì fún Ẹgbẹ́ àwọn Òǹkọ̀wé Nàìjíríà láti ọdún 1998 sí 2000, ní ìdìbò ti Dọ́kítà Wale Okediran sí àpapọ̀ ìgbìmò adarí tí Ẹgbẹ́ Àwọn Òǹkọ̀wé Nàìjíríà.[3] Raji ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi aṣàtúńse ọdún 2000 ti ANA Review, àtẹ̀jáde ti egbẹ́ naa. Ní ọjọ́ kẹta oṣù kejìlá, odun 2011, níbi ayẹyẹ ọdún ọgbọ́n ìdàsílẹ̀ Ẹgbẹ́ Àwọn Òǹkọ̀wé Nàìjíríà, a dìbò yan Remi Raji gẹ́gẹ́ bi Ààrẹ ANA kọkànlá.[3]

Raji ti jẹ́ adarí àpapọ̀ ti ẹgbẹ́ PEN ilẹ̀ Nàìjíríà tí a gbédìde ni ọdún 1999 kí á tó dìbò fun gẹ́gẹ́ bi akọ̀wé ẹgbẹ́ náà, ipò tí ó dìmú títí di a position osù kejì, ọdún 2010. Ní àsìkò yìí, Raji darí ibi ìkọ́ni àgbáyé àti and àwọn ète ìpàdé ti ẹgbẹ́ PEN tilẹ̀ Áfíríkà láàrin Áfíríkà àti ní ilẹ̀ aláwọ̀ funfun. A tún yàn lápapò gẹgẹ bí adarí akọ̀wé àkọ́kọ́ tí PAN, àjọ PEN ilẹ̀ Áfríkà, ní ìpàdé ìyàtọ̀ ní ọjọ́ kejìlèlógùn oṣù kọkànlá, ọdún 2003 ní ilẹ̀ Mexico.[3]

Ní Yunifásítì rẹ, Yunifásítì ilẹ̀ Ìbàdàn , ó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n ti ẹ̀ka èdè gẹ̀ẹ́sì àti àwọn èdè Áfíríkà àti àròkọ kíkọ, ó sì ti sìn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ipò ìṣèjọba tí ó yọrí sí yíyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi orí ẹ̀ka ẹ̀kọ́ tí èdè gẹ̀ẹ́sì ní ọdún 2011.Lẹ́yìn ọdún kan ní ipò yìí, a yàn gẹ́gẹ́ bí Gíwá fún agbo àdínì tí Áatì.[4]

Bibliography[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

References[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Sule E. Egya, Poetics of Rage: A Reading of Remi Raji's Poetry, Ibadan: Kraft Books, 2015, p. 17.
  2. Remi Raji. Archived 2012-03-21 at the Wayback Machine. Dublin Quarterly, 2005. Retrieved 8 July 2011.
  3. 3.0 3.1 3.2 3.3 3.4 Adedoyin, wole (2020-02-26). "SYNW congratulates Prof Remi Raji on Conferment of Chieftaincy title of Mogaji, Adegboro Clan". NNN NEWS NIGERIA (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-05-27. 
  4. admin (2020-02-24). "UI Professor, Aderemi Raji, Becomes Mogaji Of Historic Adegboro Compound". OyoInsight (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-05-23. 

External links[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àdàkọ:Authority control