Sam aluko

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Sam aluko
Chairman National Economic Intelligence Committee
In office
1994–1999
Arọ́pòIbrahim Ayagi
Economic Adviser
In office
1979–1983
GómìnàAdekunle Ajasin
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí
Samuel Aluko

(1929-08-18)Oṣù Kẹjọ 18, 1929
Ode-Ekiti
AláìsíFebruary 7, 2012(2012-02-07) (ọmọ ọdún 82)
London
Ọmọorílẹ̀-èdèNigerian
(Àwọn) olólùfẹ́Joyce Aluko
Àwọn ọmọ
OccupationEconomist
ProfessionAcademic

Samuel Àlùkò (August 18, 1929 – February 7, 2012) jẹ́ gbajúgbajà ọmọ Nàìjíríà onímọ̀ ètò ọrọ̀ ajé àti ọ̀mọ̀wé tó kọ oríṣìíríṣìí àwọn ìwé tí ó yànnàná àwọn àlàkalẹ̀ ìjọba lórí àwùjọ àti ètò ọrọ̀ ajé. Àlùkò tún kó ipa olùdámọ̀ràn fún àwọn aṣíwájú Olóṣèlú bí i Obafemi Awolowo àti Sani Abacha. Ànfàní ìkẹyìn yìí ni wọ́n lè pé ó ṣàjòjì nítorí i bí ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé Àlùkò ṣe jẹ́ àtakò ńlá sí àwọn àìṣe déédé ìjọba.[1]

Èròńgbà ètò ọrọ ajé àti ti òṣèlú Àlùkò jẹ́ ti bíbu ẹnu àtẹ́ lu bámúbámú la yó láàárin àwọn olóṣèlú àti mímú àlékún bá owó tí ìjọba ń pa wọlé, gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti mú kí ìdàgbàsókè ọrọ̀ ajé wà. Ó jẹ́ ayànnàná lórí ètò ọrọ̀ ajé ìlú ó sì tún jẹ́ fi ojú lámèétọ́ wo àwọn àlàkalẹ̀ àwọn báńkì onídàgbàsókè ti ìlẹ̀ òkèrè tòun ti àwọn àlàkalẹ̀ nípa ipò tí ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà wà àti àwọn àbà tó lè mú ojútùú sí àwọn ìṣòro à-jẹ-mọ́- ètò-ọrọ̀-ajé wá.[2]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Late Professor Sam Aluko and I". Punch Newspapers. 2022-02-08. Retrieved 2023-12-06. 
  2. "Making a Statement". State Magazine. 2023-08-15. Retrieved 2023-12-06.