Vanderkloof Dam

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Àwòrán Vanderkloof Dam

Vanderkloof Dam (ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ PK Le Roux Dam) wà ní ìsúnmọ́ 130 kilometres (81 mi) ìbọ́sílẹ̀ láti Gariep Dam àti pé odò Orange ní apá Gúúsù ilẹ̀ Áfíríkà ni ó ti ṣàn wá. Vanderkloof Dam jẹ́ ìdídò kejì tí ó tóbi jùlọ ní apá Gúúsù ilẹ̀ Áfíríkà (ìwọ̀n), tí ó ní odi ìdidò tí ó ga jùlọ ní Orílẹ̀-èdè ní 108 metres(ìwọn 354). Ọdún 1977 ni wọ́n ṣí ìdídò náà; ó ní agbára ti 3,187.557 million cubic metres (2,584,195 acre⋅ft) àti agbègbè pẹrẹsẹ ti 133.43 square kilometres (51.52 sq mi) nígbàtí ó bá kún. Àwọn odò mìíràn tí ó ń ṣàn sínú ìdídò yìí ni Odò Berg, àwọn ìṣàn méjì tí kò ní orúkọ tí ó ń ṣàn láti ọ̀nà Reebokrand, Odò Knapsak, Paaiskloofspruit, OdòSeekoei , Kattegatspruit àti Odò Hondeblaf, ní ìtọ́sọ́nà aago.

Ìlú VanderKloof ti fi ìdí múlẹ̀ sí apá òsì etídò ti ìdídò náà, pẹ̀lú ọ̀nà àbáwọlé ti ìlú náà wà ní ọ̀nà tí ó wá láti odi ìdídò náà, pẹ̀lú àwọn ibi ìsinmi àti àwọn pápá ìtura bí i Rolfontein Nature Reserve ( Àwọn fọ́tò Wiki Commons )

Àwọn àwòrán[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]