Yéwándé Akinọlá

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Yewande Akinola
Ọjọ́ìbí1985
Ibadan, Nigeria
Iléẹ̀kọ́ gígaCranfield University
University of Warwick
EmployerLaing O'Rourke
Gbajúmọ̀ fúnDesign Engineering

Yéwándé Akinọlá tí a bí ní ọdún 1984 jẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ àgbà tó ń ṣiṣẹ́ lórí ìpèsè omi. Ó ń ṣiṣẹ́ fún Laing O'Rourke gẹ́gẹ́ bíi Pricincipal Engineer. Ó sì máa ń ṣolóòtú ètò orí afẹ́fẹ́ kan lórí ìmọ̀ ẹ̀rọ ní Channel 4 àti National Geographic.

Ètò-èkó rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọdún 1984 ni a bí Akinọlá sórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó máa ń ya ilé kékeré nígbà tí ó ṣì wà lọ́mọdé.[1] Bàbá rẹ̀ ni J. M Akinola, tí ó jẹ́ Permanent Secretary ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nígbà kan rí.[2] Akinọlá kẹ́kọ̀ọ́ lórí Engineering Design and Appropriate TechnologyUniversity of Warwick tí ó parí ní ọdún 2007. Nígbà tí ó ṣì wà ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga, ó jẹ́ mechanical engineer fún Thames Water. Ní ọdún 2007, ilé-iṣẹ́ Arup gbà á síṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi Design Engineer. Nígbà tó ṣì ń ṣiṣẹ́ náà, ó gboyè master's degree ní Cranfield University lọ́dún 2011.[3]

Iṣẹ́ tó yàn láàyò[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Akinọlá ni olùdásílẹ̀ Global Emit Project, tó máa ń kọ́ àwọn ọ̀dọ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí ó nífẹ̀ẹ́ sí ìmọ̀ ẹ̀rọ tó sì máa ń tọ́ wọn sọ́nà.[4][5]

Lọdún 2010, Akinọlá ṣagbátẹrù ètò Titanic: The Mission for Channel 4[6] àti National Geographic Society.[7] Ní ọdún 2012, ó jẹ́ adájọ́ fún ètò Queen Elizabeth Prize for Engineering[8] Lọ́dún 2012 bákan náà, ó wà lára àwọn tí wọ́n yàn fún IET Young Woman Engineer of the Year Award, òun sì ni ó gba àmì-ẹ̀yẹ náà.[9] Ó sì ti jẹ́ olóòtú fún CBeebies àti Yesterday TV.[10][11][12] Akinọlá ti hàn lórí rédíò BBC rí.[13] Ní ọdún 2014, Akinọlá ṣe Rainwater Harvesting System.[14][15]

Ní ọdún 2013, Akinọlá ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Girl Guiding ní UK láti gba àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin níyànjú kí wọ́n jẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ.[16] Wọ́n ṣàfihàn Akinọlá nínú ìkéde "Designed to Inspire" ti Royal Academy of Engineering.[17] Wọ́n tún ṣàfihàn rẹ̀ nínú ìkéde "Create The Future" ti QEPrize lọ́dún 2014.[18] Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n pè láti sọ̀rọ̀ ní ayẹyẹ ti Ada Lovelace lọ́dún 2016.[19] Wọ́n ṣàfihàn rẹ̀ nínú ìkéde "Portrait of an Engineer" ti Institution of Engineering and Technology lọ́dún 2017.[20]

Ààtò àwọn àmì-ẹ̀yẹ tó ti gbà[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

1998 - Nigerian National Mathematics Award[2]

2009 - UK’s Society of Public Health Engineers Award for Young Rising Star[3]

2012 - Exceptional Achiever Award by the Association for Black Engineers (AFBE-UK)[2]

2012 - Young Woman Engineer of the Year from the IET[21]

2013 - Management Today’s top 35 women under 35[22]

2014 - PRECIOUS Award for Outstanding Woman in STEM[23]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Yewande Akinola". ZODML (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2018-02-04. 
  2. 2.0 2.1 2.2 "Yewande Akinola wins Exceptional Achiever award – Arup [UK"] (in en-US). emotanafricana.com. 2012-11-28. Archived from the original on 2019-04-19. https://web.archive.org/web/20190419162036/https://emotanafricana.com/2012/11/28/yewande-akinola-wins-exceptional-achiever-award-arup-uk/. 
  3. 3.0 3.1 "2012 Young Woman Engineer of the Year finalists announced - Engineering Opportunities". engopps.com. Retrieved 2018-02-04. 
  4. "About us – Low Cost Sustainable Housing". lcshr.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2018-02-05. Retrieved 2018-02-04. 
  5. "Girl Power: STEM Solutions Towards a Sustainable World conference | Long Road Sixth Form College". www.longroad.ac.uk (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2017-11-13. Archived from the original on 2018-02-05. Retrieved 2018-02-04. 
  6. Agard, Karlene. "Megaproject Trends For 2019: Yewande Akinola On The Next Frontier In Design". Forbes (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-03-11. 
  7. "Titanic: The Mission - Channel 4 - Info - Press". www.channel4.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2018-02-04. 
  8. "Trophy 2013 - Queen Elizabeth Prize for Engineering" (in en-GB). Queen Elizabeth Prize for Engineering. http://qeprize.org/trophy-2013/. 
  9. IET (2012-12-03), The IET's Young Woman Engineer of the Year (YWE) Award Finalists 2012, retrieved 2018-02-04 
  10. "Yewande Akinola". IMDb. Retrieved 2018-02-04. 
  11. "Mile High City, Absolute Genius: Monster Builds - Credits - BBC - CBBC". BBC (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2018-02-04. 
  12. Yewande Akinola (2018-02-01), Yewande's features, retrieved 2018-02-04 
  13. "Engineer Yewande Akinola explains her most exciting projects., Sheila Hancock; Engineering; Empty nesting and dependent children, Woman's Hour - BBC Radio 4". BBC (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2018-02-04. 
  14. "RAINWATER HARVESTING SYSTEM". Patent Scope. Retrieved 2018-02-04. 
  15. "Interview with Yewande Akinola: Inventer & Design Engineer | Shedistinction". www.shedistinctionblog.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2018-02-05. Retrieved 2018-02-04. 
  16. girlguiding (2013-02-21), Yewande Akinola, retrieved 2018-02-04 
  17. Royal Academy of Engineering (2013-06-04), Yewande Akinola - Designed to Inspire - Royal Academy of Engineering, retrieved 2018-02-04 
  18. Queen Elizabeth Prize for Engineering (2014-02-27), Create the Future - Yewande Akinola, retrieved 2018-02-04 
  19. Finding Ada (2016-12-12), Engineering for Global Development & Sustainability, Yewande Akinola at Ada Lovelace Day Live 2016, retrieved 2018-02-04 
  20. "Portrait of an Engineer - Faraday Secondary". faraday-secondary.theiet.org (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2019-01-23. Retrieved 2018-02-04. 
  21. "The IET Young Woman Engineer of the Year Awards - IET Conferences". conferences.theiet.org (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2018-02-04. 
  22. "35 Women Under 35: Meet your next boss". https://www.managementtoday.co.uk/35-women-35-meet-next-boss/article/1189136. 
  23. "Entrepreneur of the year puts prison past behind her" (in en). Archived from the original on 2019-01-24. https://web.archive.org/web/20190124152251/https://www.voice-online.co.uk/article/entrepreneur-year-puts-prison-past-behind-her.