Àròfọ̀ Lórí Ewúrẹ́
Ìrísí
(Àtúnjúwe láti ÀRÒFỌ̀ LÓRÍ EWÚRẸ́)
Ewúrẹ́ jẹ́ ẹran ilé
Ó máa ń jìyà púpọ̀
Bí wọ́n bá na ewúrẹ́
Á gbọn etí méjì pẹpẹ
Á tún padà sí
Ibi tí wọ́n tí nà án lẹ́ẹ̀kan
Ẹ̀yin ọmọdé ẹ gbọ́
Ẹ má ṣe bí ewúrẹ́
Ẹran aláìgbọràn
Kúrò, kúrò, kúrò ń bẹ̀.