Àdàkọ:Ayoka Ose/6
Orúkọ dàbí àmì ìdánimọ̀ tí a fi ń dá ẹnìkọ̀ọ̀kan mọ̀ orúkọ ló jẹ́ kí á dá Táyé mọ̀ yàtọ̀ sí Kẹ́hìndé, káàkiri àgbáyé ní a sì tí ń lo orúkọ, ní ọ̀pọ̀ ìgbà orúkọ sì máa ń fi bí ènìyàn ṣe jẹ́ láwùjọ hàn àti wí pe orúkọ ẹni le buyì fún ènìyàn láwùjọ. Ìṣọmọlórúkọ láàárín àwọn Yorùbá dàbí ìgbà tí a ń ṣe ọdún ní torí pé tọmọ, taya, tẹbí, tará, tìyekan àti àwọn alábáse gbogbo ní yóò pésẹ̀ sí ibẹ̀, láyé àtijọ́ ọjọ́ keje ní wọ́n máa ń sọ ọmọ obìnrin lórúkọ nígbà tí tọmọ kùnrin sì jẹ́ ọjọ́ kẹsàn-án èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú èrò àti ìgbàgbọ́ wọn pé eegun méje ni obìnrin ní nígbà tí tọkùnrin jẹ́ mẹ́sàn-án ṣùgbọ́n lóde-òní ohun gbogbo ti yí padà àti obìnrin àti ọkùnrin ni wọ́n ń sọ lórúkọ lọ́jẹ́ kẹjọ. Bí a ṣe ń ṣe ìṣọmọlórúkọ yàtọ̀ láti idílẹ́ sí ìdílé ṣùgbọ́n ní ọjọ́ ìṣọmọlórúkọ yìí àgbà ilé lóbìnrin yóò gbé ọmọ yìí lọ́wọ́ yóò sì fí ẹsẹ̀ rẹ̀ tẹ ilẹ̀, orísìírísìí nǹkan ní wọ́n ń lò níbi ìsọmọlórúkọ bíi. Oyin, Epo, Iṣu, Ẹja, Iyọ̀, Omi, abbl láti jẹ́ kí ọmọ yìí mọ bí ayé se rí wọn yóò fí gbogbo ohun tí a kà sókè yìí tọ́ ọmọ lẹ́nu wò, wọ́n sì máa ń wọ́n omi sí ọmọ yìí lára tàbí kí wọ́n da omi sí orí páànù kí wọn ó wá jẹ́ kí ó kán si ọmọ yìí lára. Orúkọ dabí fèrèsé tí ó fi ÀṢÀ, Èsìn, Iṣé àti ìgbàgbọ́ àwọn Yorùbá hàn. Oríṣìíríṣìí nǹkan la fi ń sọmọ lórúkọ bíi OYIN, EPO, IYỌ, ẸJA, OMI abbl. Oríṣìíríṣìí nǹkan ló le yọrí sí orúkọ tí a sọ ọmọ