Àdàkọ:Ayoka Ose/9

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ila nomba gidi
Ila nomba gidi

Ninu imo mathematiki, nomba gidi (real number) ni a mo si awon nomba ti a le kole gege bi nombamewa (decimal) ti ko lopin. Fun apere 2.4871773339…. Awon nomba gidi je nomba onipin, nomba bi 42 ati −23/129, ati nomba alainiipin, nomba bi π ati gbòngbò alagbarameji 2 (square root) ti won si se fihan gege bi ojuami (point) ni ori ila nomba to gun ni ailopin.

A n pe awon nomba gidi be lati le seyato si awon nọ́mbà tósòro (complex number). Ni aye atijo awon onimo isiro mo nomba tosoro gege be nomba tikosi (imaginary number).

Nomba gidi le je onipin tabi alainipin; o le je nomba aljebra tabi nomba tikonionka (transcendental number); be si ni won le wa ni apaotun, ni apaosi tabi ki won o je odo.

A n fi nomba gidi se iwon awon opoiye to je wiwapapo (continuous). O se se ka fi won han gege bi nombamewa to ni itelentele (sequence) eyonomba (digit) ti ko lopin lapa otun ojuami nombamewa (decimal point); a le fi won han bayi 324.823211247…. Awon ami bintin meta to wa leyin nomba yi tumosi pe awon eyonomba miran si n bo leyin.