Badagry

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Àgbádárìgì)
Àgbádárìgì
Ìlú
Ọjà Àgbádárìgì ní ọdún 1910
Ọjà Àgbádárìgì ní ọdún 1910
Ifihàn Àgbádárìgì ní ìlú Èkó
Ifihàn Àgbádárìgì ní ìlú Èkó
Àgbádárìgì is located in Nigeria
Àgbádárìgì
Àgbádárìgì
Ibi tí Àgbádárìgì wà ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà
Coordinates: 6°25′N 2°53′E / 6.417°N 2.883°E / 6.417; 2.883
Orílẹ̀ ÈdèNigeria
Ìpínlẹ̀Ìpínlẹ̀ Èkó
LGAÀgbádárìgì
Area
 • Total441 km2 (170 sq mi)
Population
 (2006)
 • Total241,093
Time zoneUTC+1 (WAT)
Websitewww.badagrygov.org

Àgbádárìgì tí a kọ́kọ́ mọ̀ sí Gbagle láti ìbèrè jẹ́ ìlú ẹ̀bádò àti ìjoba ìbílè ní ipínlè Èkó, lórílẹ̀-èdè Nàìjíría. Àgbádárìgì gúnwà láàárín Ìlú Èkó àti orílẹ̣̀-èdè Olómìnira Benin. Èyí jásí wípé, Ó tún jẹ́ ìlú alálà Nàìjíría àti orílẹ̣̀-èdè Olómìnira Benin ni Sèmè.[1]. Gẹ́gẹ́bí àkọsílẹ̀ ètò ìkànìyàn ọdún 2006, àpapọ̀ iye enìyàn tó wà ní Àgbádárìgì jẹ́ 241,093.[2]

Àgbègbè Ìtèdósí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àgbádárìgì jẹ́ ìlú tí a tẹ̀dó si ẹ̀bádò ìwọ̀-òorùn Nàìjíría. Ó jẹ́ ìlú tó pàlà pẹ̀lú Gulf of Guinea làgbègbè gúsú. Ó wọn ìwọ̀n máìlì mẹ́tàdínlógójì (43) ní apá gúsú ìwọ̀-òorùn ti ìlú Èkó, bákan náà ó wọn ìwọ̀n máìlì mẹ́jìdínlọ́gbọ̀n (32) ní apá ìwọ̀-òorùn ní ìlú Sẹ̀mẹ̀ tí ó pàlà pẹlú orílẹ̣̀-èdè Olómìnira Benin. Gẹ́gẹ́bí erékùsù Èkó, Àgbádárìgì jẹ́ ìlú tí a tẹ̀dó sí etí omi, nítorí ìdí èyí, àyè wà láti rìnrìn-àjò gbojú omi láti Èkó sí Ìlú Porto Novo. Àlàfo tó wà láàárín òkun àti ọ̀sà dá lórí ẹ̀bádò, ní Àgbádárìgì, ó tó máìlì kan sí ara wọn. Jíjìnà àwọn òdò wònyí máa ń dá lórí irú àsìkò tí a bá wà, ó máa ń jìnnà bíi ìwọ̀n mítà mẹ́ta bí òdò kuń dẹ́nu, Ṣùgbọ́n lásìkò ọ̀gbẹḷẹ̀, ó máa ń jìnnà bíi ìwọ̀n mítà ẹyọ kan. Onírúurú ọ̀pọ̀ ẹja ló wà nínú àwọn òdò wọ̀nyí, lára àwọn ẹja tó wà nínú òdò Àgbádárìgì ni; ọ̀bọ̀kún, èpìà, àrọ̀, kókà, bongá at pompano. Omi inú àwọn odò Àgbádárìgì máa níyọ̀ nínú ní àwọn àsìkò kan, bẹ́ẹ̀ kìí níyọ̀ láwọn àsìkò mìíràn, ìṣàn omi láti apá iwọ́-oòrùn ìlú náà àti odò Yewa ló máa ń ṣàn sinu odò Àgbádárìgì.

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Interesting Facts That Put Badagry On The Map". Guardian Life. Retrieved 2018-07-21. 
  2. The area is led by a traditional chief, Akran De Wheno Aholu Menu - Toyi 1, who is also the permanent vice-chairman of obas and chiefs in Lagos State. Federal Republic of Nigeria Official Gazette Archived 2007-07-04 at the Wayback Machine., published 15 May 2007, accessed 8 July 2007